Bi Jonathan ba fẹẹ dupo aarẹ ninu ẹgbẹ wa ni 2023, aaye wa fun un -APC 

Ẹgbẹ oṣelu APC ti ni bi aarẹ tẹlẹ ni Naijiria, Ọmọwe Goodluck Ebele Jonathan, ba fẹẹ dije dupo aarẹ orilẹ-ede yii ninu ẹgbẹ oṣelu Onigbaalẹ yii, aaye wa fun un daadaa.

Akọwe apapọ ẹgbẹ APC to tún n ri si apejọpọ wọn, John Akpanudoedehe, lo sọrọ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹsan -an yii, nigba to fara han lori eto ileeṣẹ Tẹlifiṣan Channels kan to ni i ṣe pẹlu oṣelu.

Ọkunrin naa tẹsiwaju pe bi Jonathan ba fi le darapọ mọ APC, iyi ẹni to ti jẹ ọmọ ẹgbẹ tẹlẹ lawọn yoo fun un, nitori bawọn ṣe maa n ṣe ninu APC niyẹn.

Akọwe APC yii sọ pe oun ṣẹṣẹ n gbọ ọ fungba akọkọ ni, pe awọn n reti aarẹ tẹlẹ naa ninu ẹgbẹ awọn. O ni iroyin nla ni yoo jẹ, awọn yoo si ki i kabọ bii ọmọ ọlọba ni to ba wa.

Ṣugbọn o, Ọgbẹni John sọ pe Jonathan yoo ni lati ta kangbọn pẹlu awọn akopa yooku to ba ba ninu ẹgbẹ APC ko too le gba tikẹẹti o. O ni ki i ṣe pe yoo kan wọle ṣọọ lai koju ẹnikankan.

Ẹ oo ranti pe loṣu kọkanla, ọdun 2020, awọn olori APC kan ṣabẹwo si Jonathan, awọn eeyan fi sọ pe wọn fẹẹ fa oju rẹ mọra ni.

Leave a Reply