A ti ri obinrin to ṣegbeyawo pẹlu igi ẹlẹka. Laye yii kan naa la ti ri obinrin to ni oun ko ri ọkọ fẹ, to si gbe ara rẹ niyawo. To wọ aṣọ igbeyawo funfun gẹrẹjẹ, to tun gbe fulawa to rẹwa dani. Ni bayii, ọkunrin ara Indonesia yii ti ṣegbeyawo tiẹ pẹlu pọọtu ti wọn n pe ni ‘Rice Cooker’. O ni nnkan idana naa ni ololufẹ oun tootọ, o si ba a ṣegbeyawo nilana alarede, ilana ofin.
Khoirul Anam lorukọ ọkunrin to fẹ nnkan idana rẹ yii, ogunjọ, oṣu kẹsan-an, ọdun 2021 lo ṣegbeyawo naa, to si kọwọ bọwe lọdọ awọn alaṣẹ ilu wọn to n ri si igbeyawo ṣiṣe.
Funra Khoirul naa lo gbe awọn fọto igbeyawo naa sori ayelujara, o si kọ akọle kan sibẹ pe, “O funfun, ki i sọrọ pupọ, o si n se kisa ninu ounjẹ”
Boun ti wọ aṣọ igbeyawo lo fi aṣọ funfun bo nnkan idana to n pe niyawo naa loju, to si tun fẹnu ko o lapa oke, to kiisi irinṣẹ to n lo ina ọhun.
Ko si tuntun labẹ ọrun mọ lo ku ti ọpọ eeyan n wi nipa ohun ti ọkunrin yii ṣe yii, awọn to da si i sọ pe ibi tawọn eeyan kan ba ba aye yii jẹ de, aye paapaa yoo mọ pe wọn ṣe pupọ lọrọ oun.