Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Agbẹnusọ fun ileegbimọ aṣofin agba orileede yii, Sẹnetọ Baṣiru Ajibọla, lo ko ogunlọgọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC sodi l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lati sọ nita gbangba pe ki Gomina Gboyega Oyetọla maa ṣejọba lọ.
Idi ti wọn fi ṣe bẹẹ gẹgẹ bi Ajibọla ṣe wi, ko ṣẹyin bi iṣejọba rẹ ṣe n fi ti awọn araalu ṣaaju ninu oniruuru igbesẹ idagbasoke to n gbe.
Baṣiru gboṣuba fun Oyetọla lori ipa to ti ko ninu itẹsiwaju ipinlẹ Ọṣun lati ọdun mẹta to ti de ori aleefa. O ni ijọloju lo jẹ pe owo ti yoo wọle labẹnu maa n pọ ju iye tijọba n na lọ ninu eto iṣuna ijọba yii.
Bakan naa ni igbakeji gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọṣun, Ọtunba Titi Laoye-Pọnnle, sọ pe idagbasoke to ti ba ipinlẹ yii, ni pataki ju lọ, ilu Oṣogbo, ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Ọṣun, jẹ nnkan tawọn araalu gbọdọ kan saara si.
O ni awọn ko gbọdọ faaye gba ohunkohun laaye lati da ijọba yii duro, idi si niyẹn tijọba ibilẹ mẹrẹẹrin to wa ni ẹkun idibo Oṣogbo ṣe fontẹ lu saa keji iṣejọba Gomina Oyetọla l’Ọṣun.
Ninu ọrọ tirẹ, alaga kiateka ẹgbẹ APC l’Ọṣun, Ọmọọba Gboyega Famọdun, sọ pe pẹlu bi awọn ẹkun idibo marun-un ninu mẹsan-an ṣe ti fọwọ si saa keji Oyetọla, o han gbangba pe idibo abẹle lati mu oludije funpo gomina loṣu keji ọdun to n bọ yoo lọ nirọwọrọsẹ.
Famọdun parọwa sawọn ọmọ ẹgbẹ APC lati tubọ maa fọnrere iṣejọba rere to n lọ l’Ọṣun bayii, ki wọn si maa fifẹ fa awọn ti ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ wọn mọra.