Jọkẹ Amọri
Ni Mọnde, ọjọ Aje, ọsẹ yii, ni Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, ṣe ifilọlẹ bii ẹẹdẹgbẹta miliọnu owo ti awọn ontaja ati onraja le maa na lori ẹrọ ayelujara ti wọn n pe ni eNaira. Ohun ti owo ti banki apapọ ilẹ wa yoo maa ṣe amojuto ati kokaari rẹ yii wa fun ni lati maa lo o fun tita ati rira ọja kaakiri ilẹ wa ati awọn orileede mi-in, eyi ti yoo mu ki owo ṣiṣe rọrun lai maa ko owo kiṣi kaakiri.
Ọga agba ajọ banki ilẹ wa, Godwin Emiefele, ṣalaye niluu Abuja ni Mọnde, ọjọ Aje, ọsẹ yii, pe bii banki mẹtalelọgbọn lo ti bẹrẹ lilo eto naa. Bẹẹ lo sọ pe awọn eeyan to ti le ni miliọnu meji lo n lọ sori ikanni naa lojoojumọ.
Ki i ṣe pe owo ori ẹrọ ayelujara yii yoo dipo Naira ilẹ wa ti a n na, ṣugbọn yoo da bii owo ti a le fi ra tabi ta ọja lori ẹrọ ayelujara. Iyẹn ni pe loootọ owo ni, ṣugbọn ki i ṣe owo ti a le ko dani ti a maa foju ri bii owo ti a n na bayii, bo tilẹ jẹ pe iṣẹ kan naa ni wọn n ṣe.
Awọn ontaja tabi onraja meji to ba ṣi asunwọn eNaira yii yoo lanfaani lati ba ara wọn ra tabi ta lai jẹ pe wọn ko owo Naira lọwọ. Ko ni i si iyatọ ninu owo naa pẹlu eyi ti a n na, iyẹn ni pe ọgọrun-un naira beba ti a n na naa ni eyi ti wọn fẹẹ maa lo lori ayelujara ti wọn pe ni (digital money) yii naa yoo jẹ, ọkan ko ni i ju ekeji lọ niye.
Awọn ti wọn ba nifẹẹ lati lo o yoo ṣe ádákọ ọna ti wọn fi n lo o (eNAIRA Speed Wallet application) lori ẹrọ ayelujara, bi wọn ba ti gba a sori foonu wọn ni wọn yoo ni anfaani lati ṣi apo ikowosi tuntun ti wọn yoo fi maa ṣe amulo eto inawo igbalode ti wọn n pe ni eNAIRA yii, nibi ti wọn ti le ni anfaani lati ko owo sinu rẹ ki wọn si fi ta tabi raja ni awọn ẹka ti ijọba fọwọ si.
Lara anfaani to wa nibẹ ni pe wọn ko ni i yọwo ninu akaunti ẹni to ba lo o bo ṣe maa n waye teeyan ba sanwo tabi gba owo ni banki.
Yatọ si eyi, eeyan le lo ilana yii lai jẹ pe eeyan ni data lori foonu rẹ. Pe intanẹẹti wa tabi ko si ko da iṣẹ rẹ duro.
Emefiele ni loootọ o ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, ṣugbọn awọn yoo maa ṣagbeyẹwo rẹ lati ṣe awọn atunṣe to ba yẹ ti yoo mu ki lilo rẹ rọrun fun awọn eeyan orileede yii.