Faith Adebọla
“Lagbara Ọlọrun, lẹyin ti wọn ba ti bura fun mi wọle sipo Aarẹ ati olori orileede Naijiria tan, ti mo gba ọpa aṣẹ lọwọ Buhari lọjọ kọkandinlọgbọn, ọsu karun-un, ọdun 2023, ọkan Naijiria aa balẹ pẹsẹ, oju wa aa walẹ daadaa.
Gomina ipinlẹ Kogi, Ọgbẹni Yahaya Bello, lo n fọwọ sọya bẹẹ lori eto tẹlifiṣan ileeṣẹ Arise kan lọjọ Aje, Mọnde, nigba to n sọrọ nipa eto idibo sipo aarẹ to maa waye lọdun 2023.
Bello ni gbogbo nnkan amuyẹ to yẹ keeyan ni lati le de ipo olori Naijiria lo pe sara oun, o si da oun loju daadaa pe pẹlu iriri toun ti ni pẹlu boun ṣe tukọ ipinlẹ Kogi lọ sebute ayọ, ti ipinlẹ naa fi tuba-tuṣẹ, bẹẹ loun ṣe maa sapa lati tun Naijiria ṣe.
O ni: “Nigba ti mo di gomina ipinlẹ Kogi lọdun 2016, iyapa ati ipinya lori ọrọ ẹsin ati ẹlẹyamẹya gbilẹ gan-an, ipinlẹ ti iwa ọdaran ati iwa janduku n lọ bii ilẹ bii ẹni ni mo jogun. Iya aisi olori gidi n jẹ ipinlẹ ọhun nigba yẹn. Ipinlẹ ta a gbọdọ ṣiṣẹ lati mu kawọn ọdọ ibẹ wa niṣọkan, titi kan awọn obinrin, ki tẹru-tọmọ si maa da si ọrọ iṣakoso ni.
Ṣugbọn lonii, ko ti i si igba kan ti iṣọkan bii tasiko yii ṣẹlẹ ni Kogi. Iru irẹpọ bẹẹ lawọn eeyan fẹ ko waye lorileede yii, oun ni ma a ṣiṣẹ le lori.”
Bello ni ojoojumọ lawọn eeyan ti wọn fẹ koun di Aarẹ n pọ si i, ti wọn si n pariwo pe oun lawọn fẹ. O ni ko deede ri bẹẹ, wọn mọ boun ṣe le tukọ ilu lọna rere lo jẹ ki wọn maa fẹ oun nipo bẹẹ.