Igbimọ apaṣẹ pata fun ile-ẹkọ giga yunifasiti Eko (University of Lagos) ti le ọga-agba ileewe naa, Purofẹsọ Oluwatoyin Ogundipẹ kuro lẹnu iṣẹ o. Wọn ni ko ko ẹru ẹ, ko gba ile rẹ lọ lẹsẹkẹsẹ. Ṣugbọn bi awọn ti n kọwe pe ki ọga yii ko ẹru e, bẹẹ loun naa kọwe mi-in sita pe a ki i gba àkàkà lọwọ akítì, ko sẹni ti i ba èṣù du ilẹ oríta, oun ko nibi kan ti oun fẹẹ lọ.
Ni ilu Abuja ni igbimọ to ga julọ yii ti pade, ṣe awọn ni wọn n paṣẹ yunifasiti yii lorukọ ijọba apapọ, awọn ni wọn le gba ọga-agba siṣẹ, awọn naa ni wọn si le le e lọ, bo tilẹ jẹ pe wọn gbọdọ tẹ le ofin. Nibi ti wahala ti wa gan-an niyẹn o, nitori Purofẹsọ Ogundipẹ ni lile ti wọn le oun yii ko ba ofin mu, oun ko si ni i lọ, wọn kan n da ara won laamu lasan ni.
Bẹẹ ni tododo, o to ọjo mẹta kan ti ija buruku ti n waye laarin olori igbimọ apaṣẹ yii, Ọmọwe Wale Babalakin, ati Ogundipẹ ti i ṣe ọga agba nibẹ. Igba kan ti wa ti Babalakin ati awọn ọmọ igbimọ rẹ fẹẹ ṣe ipade ninu ọgba yunifasti yii ṣugbọn ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ati olukọ nibẹ lawọn ko gbọdo ri i ninu ọgba awọn. Ohun to jẹ ki wọn gbe ipade naa lọ si Abuja niyi.
Nibi ipade Abuja yii, wọn fẹsun kan Purofẹsọ Ogundipẹ pe o ṣe aṣemaṣe, o nawo ni inakuuna, o ṣi agbara lo, ati awọn ẹṣẹ mi-in bẹẹ. Awọn mejila ni ọmọ igbimọ naa ti wọn pade, nigba ti ọrọ si di ti ibo didi, awọn meje dibo pe ki wọn le e lọ, awọn mẹrin dibo pe ki wọn ma le e, ẹni kan si dibo pe ki wọn kan da a duro fun igba diẹ ni. Nigba ti awọn ti wọn si ni ki wọn le e lọ ti pọ ju awọn ti wọn ni ki wọn ma le e lọ, wọn paṣẹ fun akọwe igbimọ, Ọladẹjọ Azeez, pe ko kọwe idaduro fun un kiakia.
Ṣugbọn bi iwe yii ti n jade ni Ogundipẹ naa kọwe mi-in, o ni gbogbo iṣoro oun ko tọwọ ẹni meji wa bi ko ṣe lati ọdọ Babalakin, ṣugbọn o ti feeli bii ọrọ awọn oloyinbo, nitori oun ko nibi kan ti oun fẹẹ lọ, awọn yoo jọ na an tan bi owo ni. Boya ni ko jẹ ọrọ to sọ yii lo jẹ ki igbimọ naa tun sare jokoo, ni wọn ba yan adele ọga-agba tuntun fun yunifasiti Eko naa, Purofẹsọ Theophilous Ṣoyọmbọ ni.
Ko waa si ẹni to ti i mọ, boya ikún lo ni oko, bi pakute ni, o digba naa na o.