Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ileegbimọ aṣofin Ogun ti beere fun pe ki ofin ma-fẹran-jẹko ni gbangba ti Gomina Ọmọọba Dapọ Abiọdun buwọ lu loṣu to kọja bẹrẹ iṣẹ kia.
Wọn ni ki gomina ma ṣe fi ti anfaani oṣu mẹfa to fun awọn darandaran naa lati palẹmọ ṣe rara, nitori ọwọ ki i pẹ ni isa akeeke.
Ọjọbọ, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹwaa, nileegbimọ naa jokoo lọfiisi wọn l’Oke-Mosan, l’Abẹokuta, ibẹ ni aṣofin to n ṣoju Ariwa Yewa kin-in-ni, Ọnarebu Adegoke Adeyanju, ti ṣalaye pe o yẹ kijọba tete bẹrẹ igbesẹ ofin yii, nitori asiko ẹẹrun ti ija maa n saaba waye laarin awọn agbẹ atawọn Fulani to n daran kiri naa ti wọle de tan.
Ọnarebu Adeyanju sọ pe nigba ti yoo ba fi di oṣu mẹfa tijọba fun awọn eeyan naa lati fi wa ibi ti wọn yoo ti maa fun ẹran wọn lounjẹ, asiko ẹẹrun yoo ti de, ija to n mu ẹmi eeyan lọ yii si tun le waye, idi niyẹn to fi yẹ ki ofin naa bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ.
Fun idi eyi, Olori ileegbimọ, Ọnarebu Taiwo Ọlakunle Oluọmọ, ni ki Oludamọran pataki fun Gomina Dapọ Abiọdun lori ọrọ aabo, Oluṣọla Subaru, pẹlu awọn tọrọ yii tun kan ninu ijọba, tete bẹrẹ eto lori bi ofin ti gomina buwọ lu loṣu to kọja naa yoo ṣe bẹrẹ iṣẹ kia.
O ni ki gbogbo ẹka agbofinro ipinlẹ Ogun tete ṣa ara wọn jọ, ki wọn ri i pe aaye ija kankan ko yọ laarin awọn agbẹ ati Fulani, paapaa lapa Yewa ti kinni naa ti maa n saba waye.
Oluọmọ ni bi ofin yii ba tete bẹrẹ iṣẹ, yoo gba awọn agbẹ lọwọ awọn darandaran to n gba ilẹ wọn to si tun n pa wọn nipakupa.