Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, lawọn ẹgbẹ alapata ni tibu-tooro ilu Ilọrin, ti i ṣe olu ipinlẹ Kwara, bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ meji, latari ọwọngogo maaluu.
Alaga awọn alapata ni isọ ẹran Olusọla Saraki, to wa ni agbegbe Akerebiata, niluu Ilọrin, Alaaji Lam Abdulrasaq, to ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe ohun to fa ọwọngogo maaluu ni awọn agbebọn ati ajinigbe ti wọn n ṣoro bii agbọn, ti awọn ọmọ ẹgbẹ awọn o si ri ere jẹ mọ, nitori ojoojumọ ni wọn n panu owo iyebiye latari bi awọn onibara ṣe n tadi mẹyin ti wọn ba ti na ẹran, ti wọn o si ni i le ra a.
Alaga ẹgbẹ ọhun waa rọ ijọba ipinlẹ Kwara, labẹ ijọba Gomina Abdulrazak, pe ki wọn wa ọna lati ran ẹgbẹ naa lọwọ tori pe ọna ọfun bayii ni ọna ọrun, ati pe latigba ti Korona ti de, ti awọn ajinigbe n ṣe tiwọn, ti gbogbo nnkan si dojuru fun awọn alapata, ijọba o ri tawọn ro rara.
Gbogbo awọn agbegbe to ṣe pataki ti wọn ti n pẹran nigboro Ilọrin ti ALAROYE de bii ọja Ipata, Mandate, Oja-Tuntun, to fi mọ ibuṣọ to jẹ ti aladaani ni wọn tẹle ofin iyanṣẹlodi ọlọjọ meji ti ẹgbẹ naa kede rẹ.