Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọwọ awọn ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ọṣun ti tẹ ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Kẹhinde Babalọla, lori ẹsun idigunjale ati ifipabanilopọ.
Ọmọ bibi ilu Ogbomọṣọ ni Kẹhinde, ṣugbọn ilu Okuku nijọba ibilẹ Odo-Ọtin, nipinlẹ Ọṣun, lo ti n ṣiṣẹ awọn to n tun mọto akoyọyọ (truck) ṣe.
Lọjọ Mọnde to kọja la gbọ pe ọmọkunrin naa lọ si ositẹẹli awọn akẹkọọ fasiti kan ninu ilu Okuku pẹlu ibọn. Lẹyin to ji foonu ati obitibiti owo nibẹ lo tun fipa ba akẹkọọ-binrin kan lo pọ.
Nigba ti awọn Amọtẹkun gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni wọn bẹrẹ iwadii, ko si pẹ rara tọwọ fi tẹ Kẹhinde, to si jẹwọ awọn iwa laabi to ti hu sẹyin.
Bakan naa lọwọ tun tẹ ọmọ ọdun mejidinlogun kan, Timilẹyin Afọlabi, niluu Ọyan, lori ẹsun idigunjale.
Gẹgẹ bi Alakoso ẹṣọ Amọtẹkun l’Ọṣun, Amitolu Shittu, ṣe sọ, alaabọ ẹkọ ni Timilẹyin, ile ojiṣẹ Ọlọrun kan lo ti kọkọ jale, nibẹ lo si ti ji ibọn to fi n jale kaakiri.
Amitolu sọ siwaju pe awọn ti fa Kẹhinde ati Timilẹyin le awọn oṣiṣẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ lọwọ fun iwadii.