Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, lawọn mọlẹbi kede iku oluranlọwọ pataki si Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq, lori ọrọ ẹṣin Kristiẹni, Dokita Samuel Olusegun Adedayọ, pe o ku lẹyin aisan ranpẹ.
Wọn ni aisan ọkan (cancer) lo pa Pasitọ Adebayọ, to ti figba kan jẹ pasitọ ni ileejọsin ECWA ti agbegbe Ọlọrunshogo, nijọba ibilẹ Guusu Ilọrin (South), nipinlẹ Kwara.
Gomina Abdulrasaq ti kẹdun pẹlu mọlẹbi ati ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi lapapọ. O juwe iku oloogbe naa gẹgẹ bii adanu nla fun mọlẹbi ati ipinlẹ Kwara, o tẹsiwaju pe Adedayọ ni ojusun rere, to si ti kopa ribiribi nibi iṣejọba to n bẹ lode, to si n soju awọn Onigbagbọ ati ijọba ibilẹ Ifẹlodun to ti wa daadaa lọdọ ijọba. Gomina ni iku oloogbe naa fi n ran wa leti ni pe dandan ni iku, ko si ẹmi ti ko ni i tọ ọ wo.
Awọn mọlẹbi oloogbe ni awọn yoo maa kede eto isinku laipẹ.