Faith Adebọla
Niṣe nijọba ti geeti to wọle si awọn ileeṣẹ ọba gbogbo lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, mọ awọn ti wọn ko fi ẹri han pe awọn ti gba abẹrẹ ajẹsara Korona, ita ni aja n gbe nijọba fi ọrọ wọn ṣe.
Iṣẹlẹ yii waye latari gbedeke tijọba fi lede ninu oṣu kẹwaa, ọdun yii, pe ki gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ ti wọn ti wa nile fungba pipẹ latari ofin konilegbele to waye nigba ti arun Korona n ja ranyin tete lọọ gba abẹrẹ ajẹsara Korona ki wọn too bẹrẹ iṣẹ pada lawọn ọfiisi wọn gbogbo.
Alaga igbimọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari gbe kalẹ lori ajakalẹ arun COVID-19 ọhun, Ọgbẹni Boss Mustapha, lo kede pe ijọba ti fọwọ si ṣiṣi awọn ileeṣẹ ọba ati sẹkiteria ijọba apapọ lọjọ ki-in-ni, oṣu kejila, ọdun 2021 yii.
Amọ kidaa awọn ti wọn ti gba abẹrẹ ajẹsara Korona ni wọn maa gba laaye lati wọle o, tori dandan lowo ori, ọran-anyan laṣọ ibora ni. Awọn ti yoo wọle gbọdọ ni kaadi ẹri pe wọn ti gbabẹrẹ naa, wọn si gbọdọ fi kaadi naa han awọn ẹṣọ lẹnu geeti ki wọn too le ṣilẹkun fun wọn.
Yatọ si gbigba abẹrẹ ajẹsara, awọn ti wọn ti lọọ ṣayẹwo arun Korona, ti ẹri si fi han pe ṣaka lara wọn da, tabi ti wọn ti ni arun naa tẹlẹ, ṣugbọn tara wọn ti ya, le wọle.
Lẹnu geeti awọn ileeṣẹ ọba ati ẹka iṣẹ ijọba apapọ l’Abuja, niṣe logunlọgọ awọn oṣiṣẹ paro jọ, awọn mi-in lara wọn n bẹbẹ boya wọn le ṣoju aanu si wọn, ṣugbọn wọn o ṣi geeti fun wọn.
Awọn kan lara awọn oṣiṣẹ naa ko ti i gba abẹrẹ ajẹsara ọhun, wọn lawọn ro pe ijọba maa sun gbedeke naa siwaju latari bi ẹgbẹ awọn lọgaa-lọgaa lẹnu iṣẹ ọba (Association of Senior Civil Servants of Nigeria) ṣe parọwa pe kijọba sọ gbedeke naa di ibẹrẹ oṣu kẹta, ọdun to n bọ ni.
Awọn mi-in lawọn ti gbabẹrẹ naa, ṣugbọn kaadi awọn ti sọnu, awọn o si fẹẹ gba abẹrẹ ajẹsara mi-in ko ma lọọ pọ ju, bẹẹ lawọn kan ni awọn gbagbe kaadi awọn sibi tawọn ti n tirafu bọ ni.
Pẹlu bijọba ṣe kede pe ẹya Omicron ti wọn lo buru gidi lara ẹya arun Korona ti de Naijiria, Boss Mustapha ni reluwee to ti lọ lawọn to fẹ kijọba sun gbedeke naa siwaju, n ṣẹwọ si.