Faith Adebọla, Eko
Ajọ LASEMA to n ri si iṣẹlẹ pajawiri l’Ekoo, (Lagos State Emergency Management Agency), ti fẹsun kan dẹrẹba bọọsi akero to ja bọ sinu ẹrọfọ latori biriiji sinu ẹrọfọ eti ọsa, lọjọ Aje, Mọnde yii, wọn ni ere asapajude, iwa aibikita ati aitẹle ofin lo ṣokunfa ijamba naa.
Ọmọdebinrin ọmọọdun mejọ kan la gbọ pe o ku ninu ijamba naa, ọgọọrọ awọn ero mẹtadinlogun yooku si fara gbọgbẹ loriṣiiriṣii, titi kan awakọ mọto Varagon ti wọn kun lọda funfun ọhun.
Wọn ni ode ariya kan to n lọ lọwọ laafin ọba Oworonṣoki lawọn eeyan naa n lọ, oriṣiiriṣii kula ounjẹ ati ọti ẹlẹridodo ni wọn di sinu ọkọ naa, gbogbo ounjẹ ọhun lo fọn ka sinu ẹrọfọ nigba ti ijamba naa waye.
Ọga agba ajọ LASEMA, Dokita Olufẹmi Oke-Ọsanyintolu, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita pe iwadii tawọn ṣe nigba tawọn debi iṣẹlẹ naa fihan pe awakọ bọọsi naa ko le ṣakoso ọkọ ti nọmba rẹ jẹ LAGOS LSD 184 XV naa mọ, latari ere asapajude to sa gun biriiji kekere kan to wa laduugbo Sand-filling, lagbegbe Oworonṣoki, nitosi afara Third Mainland Bridge.
Bi bọọsi naa ṣe re bọ latori biriiji ọhun lo fẹgbẹ lelẹ sinu ẹrọfọ to wa labẹ biriiji ọhun, wọn lawọn aladuugbo gbiyanju lati yọ awọn eeyan to fara pa jade, ki awọn oṣiṣẹ ijọba too de ibi iṣẹlẹ naa, ṣugbọn oju-ẹsẹ ni wọn lọmọbinrin to doloogbe naa ti dakẹ.
Ọgbẹni Oke-Ọsanyintolu ni ọpọ awọn eeyan ti wọn doola ẹmi wọn ni wọn fara gbọgbẹ pẹẹpẹẹpẹẹ, ṣugbọn obinrin ẹni ogun ọdun kan ṣeṣe gidi, latari bii ọkọ naa ṣe run un mọlẹ, wọn si ti gbe e lọ sọsibitu fun itọju akanṣe.
O lawọn ero ọkọ naa sọ p’awọn ṣekilọ fun dẹrẹba ọhun pe ere to n sa ti pọ ju, ṣugbọn ko dahun.
Ṣa, wọn ti fi katakata fa awoku bọọsi naa jade, wọn si ti wọ ọ lọ si teṣan ọlọpaa Alongẹ, lagbegbe Oworonṣoki.
Awọn ọlọpaa ṣi n ba iwadii niṣo lori iṣẹlẹ ọhun.