Faith Adebọla
Eeyan mẹta lo pade iku ojiji nibi ijamba mọto kan to waye laarin ọlọkada ati ọkọ akoyanrin kan ni Ibudokọ Eleganza, ni Lẹkki, niluu Eko, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Gẹgẹ bi awọn tiṣẹlẹ naa ṣọju wọn ṣe sọ fun akọroyin wa, ọlọkada kan ni wọn lo fi oju ọna rẹ silẹ, to lọọ gba ọna ọlọna, to si ṣe bẹẹ doju kọ awọn ọkọ to n bọ.
Lojiji lọkọ nla kan to ko yanrin pade rẹ, nibi to si ti n gbiyanju lati pẹwọ fun ọlọkada naa ko ma baa gba a lo ti lọọ tẹ eeyan mẹta pa.
Niṣe ni gbogbo agbegbe naa daru, ti awọn eeyan si ya bo mọto naa ati dẹrẹba to wa a. Oju-ẹsẹ ni wọn dana si i, ti wọn si gbegi di gbogbo oju ọna, ti iwaju ko ṣee lọ, bẹẹ ni ẹyin ko ṣee pada si.
Iṣẹlẹ yii lo fa sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ọkọ, ti awọn eeyan si wa ni oju kan na fun igba pipẹ.
Niṣe ni awọn ero ti inu n bi nitori awọn mẹta to ku naa kọju ija sawọn ọlọpaa to waa pẹtu si wahala naa, nigba ti apa wọn ko si feẹ ka awọn ero naa, niṣe ni wọn sa wọ ileeṣẹ Eleganza to wa nitosi ibi ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ fun aabo ẹmi wọn.
Gburugburu ni mọto naa jona. Awọn agbofinro lo pada waa pẹtu si iṣẹlẹ naa ti gbogbo nnkan fi lọ silẹ, ti wọn si gbe awọn to padanu ẹmi wọn ninu ijamba naa lọ si ile igbokuu-pamọ-si.