Afi ki awọn oṣonu, awọn ti inu wọn ki i dun nigba kọọkan, tabi awọn ti inu wọn ba maa n dun ni gbogbo igba, ti wọn ko si raaye ṣe afihan rẹ bo ṣe tọ yaa tete gba orileede kan ti wọn n pe ni Finland, niluu awọn alawọ funfun lọ o.
Ohun ti awa ri gbọ ni pe ibanujẹ kan ko si fun awọn eeyan ilu naa, nigba gbogbo ni inu wọn maa n dun bii oyin, ti wọn si maa n yọ ṣẹṣẹ. Idunnu naa si pọ debii pe awọn ni wọn gba ami-ẹyẹ orileede ti inu rẹ maa n dun ju lọ lagbaaye fun igba karun-un.
Nibi ayẹwo atigbadegba kan ti ajọ agbaye UN, maa n ṣe ni wọn ti fidi eyi mulẹ. Wọn ni orileede naa ni inu awọn eeyan wọn maa n dun ju lọ ni gbogbo agbaye.
Afghanistan ni orileede ti inu wọn maa n bajẹ ju lọ, nigba ti Lebanon ati Venezuela n tẹle wọn gbagbaagba.
Ọrọ aje ilẹ Lebanon ti ko rẹrin-in rara lo jọ pe o fa bi orileede naa ṣe wa ninu awọn ilẹ ti inu wọn ki i dun lagbaaye.
Ni awọn orileede ti wọn n tọju awọn eeyan wọn daadaa ni Serbia, Bulgaria ati Romania wa.
Ṣugbọn awọn kan ti n sọrọ o, wọn ni awọn to ṣe ayẹwo naa ko ṣe daadaa rara, wọn ni nibo ni wọn fi orukọ Naijiria si ti wọn ko fi si ipo kin-in-ni ninu awọn orileede ti inu wọn bajẹ ju lọ lagbaaye, nitori ko si ohun kan bayii teeyan le ni o n mu inu ẹni dun ni Naijiria yii. Ṣe ọrọ aje wa ni, abi ti ina mọnamọna to n fojoojumọ ṣe mọnamọna, abi ti eto aabo, ka ma ti i sọ ti ijọba Naijiria ti wọn n mu aye le koko fun gbogbo araalu. Wọn ni ilẹ Naijiria lo yẹ ko gba ipo kin-in-ni.
Bakan naa ni awọn kan n sọ pe ki awọn oyinbo fun awọn ni fisa, wọn ni awọn fẹẹ lọ si orileede Finland ti inu wọn ti dun ju lọ lagbaaye. Wọn ni o lati jẹ pe ọrọ aje wọn paapaa rẹrin-in, ohun gbogbo si rọṣọmu fun wọn ni inu wọn ṣe n dun bẹẹ.