Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ni imurasilẹ fun idibo gomina ipinlẹ Ọṣun ti yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii, ẹgbẹ oṣelu PDP ti kede Ọmọọba Kọla Adewusi gẹgẹ bii igbakeji fun oludije wọn, Sẹnetọ Ademọla Adeleke.
Ọmọ bibi ilu Ileefẹ, nipinlẹ Ọṣun, ni Adewusi, o si ti ṣe alaga ijọba ibilẹ naa ri laye iṣejọba Gomina Ọlagunsoye Oyinlọla.
Ninu ipade awọn lookọlookọ ninu ẹgbẹ naa to waye ni sẹkiteriati wọn niluu Oṣogbo lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni alaga ẹgbẹ naa, Sunday Bisi, kede pe lẹyin ọpọlọpọ iwadii ni awọn agbaagba forikori lati mu Adewusi.
O ke si awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ilu Ileefẹ ti inu n bi si yiyan Adewusi lati fọwọ wọnu, ki wọn ṣiṣẹ papọ fun aṣeyọri ẹgbẹ naa ninu idibo to n bọ.
Ninu ọrọ rẹ, oludije fun ipo gomina, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, sọ pe akoko ti to fun imọlẹ lati tan lori okunkun nipinlẹ Ọṣun.
O ranṣẹ ikilọ si Gomina Oyetọla lati bẹrẹ si i palẹ ẹru rẹ mọ nile ijọba, ko si bẹrẹ si i kọ iwe idagbere rẹ, nitori ipo naa yoo bọ lọwọ ẹ loṣu keje ọdun yii.
Adeleke fun awọn ọmọ ẹgbẹ naa nidaniloju pe ki wọn fọkan balẹ, ki wọn si ma ṣe faaye gba ẹnikẹni lati ko wọn laya jẹ rara nitori Ọlọrun wa ni iha wọn.