Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Baba ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin kan, Alagba Babatunde Benjamin, lori tun ko yọ lọwọ awọn janduku Fulani kan ti wọn ṣe akọlu si i ninu oko rẹ n’Ikakumọ Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko.
ALAROYE gbọ pe nibi ti baba agbalagba ọhun ti n ṣiṣẹ lọwọ ninu oko laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ ta a lo tan yii lawọn Fulani darandaran naa ka a mọ, ti wọn si ni ko ko gbogbo owo to wa lọwọ rẹ fun awọn.
Gbogbo ẹbẹ ti agbẹ naa bẹ wọn pe ko si kọbọ kan lọwọ oun lasiko naa ko wọ awọn janduku ọhun leti, ada ati ọbẹ daga ni wọn yọ si i, ti wọn si gun yannayanna ni gbogbo ara titi ti wọn fi ro pe o ti ku.
Awọn alaaanu kan ti wọn rin sasiko ni wọn pada gbe baba arugbo ọhun kuro ninu agbara ẹjẹ, ti wọn si gbe e lọ si ile-iwosan, nibi to ti n gba itọju lọwọ.
Iṣẹlẹ yii waye lẹyin bii ọsẹ meji ti awọn Fulani darandaran ṣe akọlu si ọkunrin agbẹ kan ninu oko kasu rẹ niluu Ikakumọ yii kan naa.
Awọn iṣẹlẹ akọlu mejeeji la gbọ pe wọn ti fi to teṣan ọlọpaa Ikarẹ Akoko leti, ṣugbọn ko sẹni ti wọn ti i ri mu ni asiko ti a n kọ iroyin yii.