Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Nibaamu pẹlu abajade igbimọ to gbọ oniruuru ẹsun iwakiwa ti awọn araalu fi kan awọn agbofinro nipinlẹ Ọṣun, Gomina Adegboyega Oyetọla loun yoo san owo gba-ma-binu fun awọn ti ọrọ naa kan.
Akọwe iroyin fun gomina, Ismail Omipidan, lo fi ọrọ naa sita laipẹ yii, o ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni eto naa yoo waye niluu Oṣogbo.
A oo ranti pe lẹyin wahala EndSars nijọba apapọ paṣẹ pe kipinlẹ kọọkan gbe igbimọ olugbẹjọ kalẹ lati gbọ awọn ẹsun naa.
Adajọ-fẹyinti, Akinwale Ọladimeji, lo ṣaaju awọn igbimọ tijọba ipinlẹ Ọṣun gbe kalẹ, wọn si ṣayẹwo oniruuru iwa bii iṣekupani, ifiyajẹni lai ṣẹ, itinimọle lai tọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ ti awọn ọlọpaa SARS hu nigba naa.
Lẹyin ijokoo wọn ni wọn gbe abọ igbẹjọ wọn lọ sọdọ gomina, ti iyẹn si ṣeleri lati gbe igbesẹ lori gbogbo nnkan to wa ninu abajade naa.
Gẹgẹ bi Omipidan ṣe wi, o ku diẹ kijọba kede igbesẹ wọn lori ẹ nijọba apapọ paṣẹ pe ki gbogbo ipinlẹ fi awọn abajade igbimọ wọn ranṣẹ si ileeṣẹ Aarẹ.
O ni ṣugbọn gẹgẹ bii gomina to fẹran idajọ ododo, to si korira iwa fifi ọwọ ọla gba ni loju, Oyetọla pinnu lati san owo-gba-ma-binu fun awọn eeyan naa gẹgẹ bi awọn igbimọ naa ṣe dabaa.
O waa ke si gbogbo awọn araalu lati jẹ oluṣọ ọmọnikeji wọn ninu iwa ọmọluabi ati iwa to tọ lawujọ.