Ọlawale Ajao, Ibadan
Ọpọ igbeyawo lo n daru nitori pe awọn ọkọ n fiya jẹ awọn iyawo wọn, ṣugbọn ni ti idile Famuyibọ, n’Ibadan, ọkọ gan-an lo kegbajare sita, o niyawo oun ti fẹẹ fi lilu baye oun jẹ.
Ile-ẹjọ ibilẹ onipo kin-in-ni to wa ni Mapo, n’Ibadan, lọkunrin naa, Williams Famuyibọ, pariwo lọ pẹlu ẹdun ọkan nigba to n rọ adajọ kootu naa lati tu igbeyawo oun pẹlu iyawo ẹ, Ṣọla Famuyibọ, ka.
O ni yatọ si pe iyawo oun maa n lu oun bii bara, ọpọlọpọ ọna lobinrin naa maa n gba fiya jẹ oun, ṣugbọn to jẹ pe apa oun ko ka obinrin ti oun fowo ara oun fẹ sile yii.
“Nigba ti iya yii fẹẹ kọja ẹmi mi, igba kan wa ti mo sa kuro nile fun iyawo mi. Gbogbo ọrọ ti mo n sọ yii ko ju inu oṣu Kin-in-ni, ọdun yii naa lọ. Bẹẹ ni Williams ṣalaye niwaju adajọ.
Ọmọ marun-un ni mo ti bi ki n too fẹ Ṣọla, ṣugbọn nitori iwa buruku rẹ, gbogbo awọn ọmọ ni wọn ti sa kuro ninu ile, ọdọ awọn ẹbi mi ni wọn pin ara wọn si kaakiri ti wọn n gbe bayii.”
O waa rọ ile-ẹjọ lati jọwọ, fopin si igbeyawo ọlọdun mejilelọgbọn to wa laarin oun pẹlu iyawo ẹ lati ọdun 1990, ko too di pe obinrin naa fi ikuuku ran oun lọ sọrun apapandodo laipẹ ọjọ.
Ṣọla ko si ni kootu l’ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ti igbẹjọ naa waye lati sọ tẹnu ẹ lori ẹjọ ti ọkọ ẹ ro mọ ọn lẹsẹ.
Eyi lo mu ki Adajọ kootu ọhun, Onidaajọ S.M. Akintayọ, paṣẹ fun akọda kootu naa lati mu iwe ipẹjọ lọ fun olujẹjọ naa, ko le waa fẹnu ara ẹ ṣalaye ohun to ba n ṣẹlẹ laarin oun atọkọ ẹ gan-an.
O waa sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹrindinlọgbọn (26), oṣu Karun-un, ọdun 2022 ta a wa yii.