Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Nnkan o ṣẹnuure fun ikọ awọn agbebọn kan ti wọn ji arinrin-ajo mẹtala gbe lagbegbe Isua Akoko, nijọba ibilẹ Guusu Ila-Oorun Akoko, lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, pẹlu bi wọn ṣe pa ọkan ninu wọn, ti wọn si tun fipa gba diẹ lara awọn eeyan ti wọn ji gbe ọhun silẹ.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe ọkọ bọọsi elero mejidinlogun kan to n bọ lati ilu Abuja lọ sipinlẹ Eko lawọn agbebọn naa da lọna, ti wọn si ji mẹtala gbe ninu awọn ero ọhun sa wọgbo lọ. Awọn mẹta pere ni wọn mori bọ lọwọ awọn janduku ọhun lọjọ naa.
Bi apapọ awọn ẹṣọ alaabo to n peṣe aabo fawọn eeyan ijọba ibilẹ Guusu Ila-Oorun Akoko ṣe gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun ni wọn ti gbera, ti wọn si n tọpasẹ awọn janduku ajinigbe naa titi ti wọn fi kan wọn lara nibi tí wọn sa pamọ si.
Ni kete tawọn agbebọn ọhun foju kan awọn ẹṣọ alaabo to n lepa wọn ni wọn ti ṣina ibọn bolẹ, ti awọn naa si n da a pada fun wọn.
Lẹyin-o-rẹyin, akitiyan awọn ẹṣọ alaabo naa pada seeso rere pẹlu bi wọn ṣe kawọ awọn ọdaran ọhun. Wọn pa ọkan lara wọn, bẹẹ ni wọn si ri diẹ gba pada ninu awọn ẹni ẹlẹni ti wọn ji gbe.
Ibi ti wọn ti ri awọn eeyan ọhun gba pada ni wọn lo to bii ogun ibusọ si ojuko ibi ti wọn ti ji wọn gbe. Olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Isua, ni wọn si kọkọ ko awọn tori ko yọ naa lọ bi wọn ti n ko wọn wọlu.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami ni igbesẹ ṣi n tẹsiwaju lati ri awọn ọdaran naa mu.