Wọn ni ẹnjinni ọkọ oju omi to fẹmi aadọjọ eeyan ṣofo ni Kwara bajẹ ni

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ijọba ipinlẹ Kwara ti fidi ẹ mulẹ pe ẹnjinni ọkọ oju omi to ko eeyan ọọdunrun lo bajẹ lojiji ninu alagbalugbu omi, eyi to  ṣokunfa ijamba to fi ẹmi eeyan aadọjọ ṣofo, ti aadọrun si dawati.

Ẹmia ilu Patigi, Alaaji Ibrahim Umar Bologi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ Kẹrinla, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, sọ pe ọọdunrun eyan ni ọkọ naa ko, awọn mẹtalelaaadọta ni wọn ri doola, aadọjọ ku, aadọrun si dawati. O tẹsiwaju pe lati ibi ayẹyẹ igbeyawo ti awọn ero naa lọọ ṣe labule Egboti, nipinlẹ Niger, ni wọn ti n dari bọ, ṣugbọn labule Egbu, nijọba ibilẹ Patigi, ni iṣẹlẹ naa ti waye ni nnkan bii aago mẹta oru ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii. O ni ẹnjinni ọkọ naa lo deede daṣẹ silẹ lojiji.

 

Alaaji Bologi ni awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ṣi n ṣiṣẹ takuntakun lati wa awọn eeyan to dawati naa bayii.

Leave a Reply