Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti ṣafihan awọn afurasi mẹtẹẹta tọwọ tẹ lori ọrọ ṣọja kan, Akingbohun Samuel Ayọmide, ẹni ti wọn lu pa niluu Ido-Ani nijọba ibilẹ Ọsẹ, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2023.
Ohun to ṣe ọpọ eeyan to wa ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Akurẹ, nibi ti wọn ti ṣe afihan awọn afurasi ọhun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹfa yii, ni kayeefi ju lọ ni ti ọjọ ori awọn ti aje iṣẹlẹ ọhun ṣi mọ lori ti ko ti i ju bii ọmọ ọdun mẹtadinlogun si ogun ọdun lọ.
Ọdun to kọja, iyẹn ọdun 2022, lawọn mẹtẹẹta ṣẹṣẹ pari nile-iwe girama, bẹẹ ni ko si eyi to ti wọn ti i gba wọle sile-ẹkọ giga lara wọn.
Ọkan ninu awọn afurasi ọhun to porukọ ara rẹ ni Sambo Ayọmide ti akọroyin wa fọrọ wa lẹnu wo lati mọ ipa to ko lori ẹsun ti wọn fi kan wọn pe wọn lu ṣọja pa ṣalaye pe oun atawọn ọrẹ oun lawọn jọ n rin lọ lọjọ iṣẹlẹ naa, o ni ibi omi ẹrọfọ kan lawọn ti pade Akingbohun to jẹ ọmọ ogun oju omi to wa ni Imeri, pẹlu ọrẹ rẹ kan ti wọn jọ n rin bọ.
O ni ibi ti Adeleke Johnson to jẹ ọrẹ oun ti fẹẹ sa si ẹgbẹ kan ki ọkada to n bọ ma baa ta omi si i lara lo ti ṣeesi fẹgbẹ gba Akingbohun, ti iyẹn naa ko si jẹ ko tutu to fi sare fun un ni igbati kan.
Sambo ni nibẹ lọrọ ti kọkọ fẹẹ dija silẹ ṣugbọn ti oun ati ẹni kẹta awọn bẹ ọkunrin ṣọja naa pe ko ma binu, ti oun ati ọrẹ rẹ si kuro lojuko iṣẹlẹ ọhun.
Lẹyin ti wọn lọ tan lo ni Johnson fa ibinu yọ, to si ni inu oun ko dun rara si bi ṣọja naa ṣe gba eti oun, ati pe oun ko ro pe ojulowo ọmọ ogun oju omi ni i ṣe.
O ni bi Johnson ṣe ranṣẹ pe ọlọkada kan ree, ẹni to gbe awọn, ti awọn si jọ tọpasẹ ṣọja yii ati ọrẹ rẹ lọ. O ni bi awọn ṣe n lọ ni oun ti fa irin kan yọ, eyi ti oun fi lu ṣọja naa lọwọ ati lẹgbẹẹ.
Lẹyin-o-rẹyìn lo ni Johnson gba irin naa lọwọ oun, ti oun ko si mọ ibi to ti fi lu ṣọja naa to fi ṣubu lulẹ, ti ko le dide mọ.
Ọmọkunrin to ni oun wa lati ijọba ibilẹ Ogorimagongo, nipinlẹ Kogi, naa ni irọ ti ko lẹsẹ nilẹ ni Johnson n pa pe oun ko ba wọn fọgi mọ ọkunrin naa lori, o ni oun gan-an lo fọgi mọ ọn labẹ ti ko fi le ta putu mọ.
Ninu ọrọ tirẹ, Johnson ni oun loun ṣeesi fẹgbẹ gba Akingbohun loootọ ko too fọ oun leti, o ni loootọ loun bẹ awọn eeyan kan lọwẹ lati lepa ṣọja ọhun ati ọrẹ rẹ lati mọ boya ọmọ ogun oju omi ni tabi bẹẹ kọ, nitori fila kan to jẹ tawọn ṣọja nikan lo de sori nigba tawọn kọkọ rira.
Ọmọkunrin naa ni oun ko ba wọn fọwọ kan an rara, o ni ọrẹ oun, Ayọ, lo la irin mọ ọn, Johnson ni kete ti oun ti fidi rẹ mulẹ pe ojulowo ṣọja oju omi ni loun ti sare gba igi ti ọrẹ oun fi n lu u lọwọ rẹ.
Johnson ni ọmọ bibi ilu Ọka Akoko loun, ṣugbọn oun n kọṣẹ lọwọ niluu Ọwọ, lẹyin ti oun pari idanwo oniwee mẹwaa. O ni ounjẹ loun waa gba lọdọ iya oun to n gbe ni Idoani lasiko ti iṣẹlẹ yii fi waye.
Shagari Francis to jẹ ẹni kẹta wọn ni oun ko ba wọn lọwọ si lilu ṣọja naa bo tilẹ jẹ pe gbogbo iṣẹlẹ ọhun pata lo ṣoju oun.
Ọmọkunrin to ni oun wa lati ipinlẹ Nasarawa ọhun ni foonu atawọn nnkan mi-in ti oun ko lọwọ ko fun oun laaye lati ba wọn lu u.
Ohun ta a gbọ ni pe ẹpọn ṣọja yii ni wọn fọ latari irin ati igi ti wọn la mọ ọn labẹ, eyi lo si ṣokunfa bo ṣe digbolulẹ, ti ko le dìde mọ.
Wọn ní ọrẹ rẹ ti wọn jọ n lọ lasiko naa, ẹni ti wọn porukọ rẹ ni Ọlaoluwa kọkọ sa asala fun ẹmi rẹ nigba ti wọn n ṣe ikọlu si wọn, oun lo sare gbe ọrẹ rẹ nilẹ lẹyin to pada de, to si gbe e pọn lọ sileewosan kan niluu Idoani, nibi ti wọn ti fidi rẹ mulẹ pe ọmọkunrin naa ti ku.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ni igbesẹ ti n lọ lọwọ lati ri awọn ẹgbẹ wọn to sa lọ mu, ki gbogbo wọn le waa foju wina ofin.