lukoro ileeṣẹ ọmọ ogun oju ofurufu ilẹ wa tẹlẹ, Ajagun-fẹhinti Sadeeq Shehu, ti sọ pe ajalu nla gbaa lo maa koju orileede yoowu ti wọn ba kan an nipa fawọn ọgagun ti wọn ṣi wa lẹnu iṣẹ pe ki wọn fiṣe wọn silẹ gẹgẹ bawọn alaṣẹ orile-ede Naijiria ṣe ṣe, eyi to mu kawọn ọgagun wọn to le ni ọgọrun-un kọwe fiṣẹ silẹ bayii.
ALAROYE gbọ pe bii ọgọrun-un ọgagun lẹnu iṣẹ ologun oju omi, ti ori ilẹ, awọn ṣoja ti oju ofurufu ni wọn ti kan an nipa fun wọn bayii pe ki wọn lọọ kọwe fiṣẹ wọn silẹ. Igbesẹ ọhun waye latari iyansipo awọn ọga ologun kọọkan ti ijọba Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ṣẹṣẹ ṣe bayii.
Ọjọ kẹta, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, ni wọn fun gbogbo awọn lọgaa–lọgaa lẹnu iṣẹ ti ọrọ naa kan pata da pe ki wọn kuro lẹnu iṣẹ naa.
Lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ lori tẹlifiṣan ‘Arise Tv’, lọjọ Eti, Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu Keje, ọdun yii, ni Ajagun-fẹyinti Sadeeq sọrọ ọhun di mimọ. O ni igbesẹ tuntun ti Aarẹ Tinubu gbe naa ki i ṣe eyi to daa rara, ti yoo si ni ipalara gidi fun ẹka ileeṣẹ ologun orile-ede Naijiria bi wọn ko ba tete ṣatunṣe sọrọ naa ni kia.
O ni ọna tawọn alaṣẹ ijọba orile-ede wa n gba yan awọn ọmọ ogun sipo ọgagun ki i ṣohun to daa rara, ti wọn si gbọdọ ṣatunṣe si i.
O ni, ‘Aimọye nnkan la gbọdọ ṣatunṣe si lorileede wa Naijiria bayii, ko le rorun rara fun olori orile-ede kan lati yan ninu awọn ọgagun bii ọọdunrun ti wọn ba gbe orukọ wọn wa siwaju rẹ pe ko yan ẹni to ba fẹ ninu wọn. Gbara to ba ti fi le yan ẹni kan laarin wọn bayii, lawọn iyooku yoo ti maa gbaradi silẹ lati fiṣẹ wọn silẹ, eyi ti ko daa to rara. Ipalara nla gbaa lo si maa mu wa fun orilẹ-ede Naijiria lọjọ iwaju bayii.
Bawọn alaṣẹ ijọba orile-ede Naijiria ba tẹle ilana yiyan awọn ọgagun sipo gẹgẹ bii agbekalẹ ileeṣẹ ologun orilẹ-ede wa ti ṣe la a kalẹ, yoo rọrun fun aarẹ tabi olori yoowu to ba ṣẹṣẹ depo lati yan ẹni to ba fẹ ninu iwọnba orukọ ti wọn ba gbe siwaju rẹ, ti ko si ni i mu wahala kankan dani rara fawọn to n bọ lẹyin.
Sugbọn akọsilẹ iwe ofin lati yan ọgagun fun Aarẹ tuntun lorileede Naijiria ko sọ pe dandan ni pe ẹnikan lo gbọdọ wa nipo naa. Bo ba wu Aarẹ tuntun, o le lọọ mu ọmọọṣẹ kan jade, ti yoo si sọ pe ẹni toun n fẹ nipo ọgagun niyi. Bi eyi ba waye, o di dandan kawọn ọga ti wọn wa niwaju rẹ lẹnu iṣẹ kọwe fipo wọn silẹ gẹgẹ bo ti ṣe fẹẹ waye lorile-ede wa bayii.