Adeoye Adewale
Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Oloye Ayọdele Fayoṣe, ti sọ idi pataki to fi ṣiṣẹ ta ko ondije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Alhaji Atiku Abubarkar, ninu ibo gbogboogbo to waye gbẹyin ninu oṣu Keji, ọdun 2023 yii.
Fayoṣe ni nitori pe ẹya kan ko gbọdọ maa fọwọ lalẹ fawọn yooku, ati pe, ipinnu oun ni pe akoko ti ẹya Yoruba maa jẹ aarẹ orileede yii la wa yii, ko si gbọdọ sohun kankan to gbọdọ da a duro tabi di i lọwọ.
Gomina tẹlẹ naa sọrọ ọhun lasiko to n sọrọ pẹlu awọn oniroyin ‘Channel TV’, niluu Eko, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹwaa, oṣu Keje, ọdun 2023 yii.
O ni oun sa gbogbo agbara oun, oun si ṣatilẹyin gidi fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu lakooko idibo naa ko baa le jawe olubori.
O ni, ‘‘Bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ PDP ko ṣe daadaa si mi, sibẹ, mo nifẹẹ ẹgbẹ naa gidi. Ohun ti mo si fẹẹ fidii rẹ mulẹ daadaa fun gbogbo eeyan ti wọn n gbọ mi ni pe ki i ṣe ẹgbẹ PDP ni mo ṣiṣẹ fun rara lasiko ibo to waye lorileede yii gbẹyin, mi o sọ asọdun rara, bẹẹ ni, mi o ki i ṣẹ opurọ eeyan.’’
Ọkunrin ti wọn maa n pe ni Osoko yii ni ojulowo ọmọ ẹgbẹ PDP ṣi loun, afi ti ẹgbẹ naa ba sọ pe awọn ko fẹ oun mọ lo ku.
‘‘Bi ẹgbẹ ko ba juwe ọna ita fun mi pe awọn ko fẹ mi mọ, ko sohun to maa le mi kuro ninu ẹgbẹ naa rara. Bi wọn ba si sọ pe awọn ko fẹ ki n jẹ ọmọ ẹgbẹ naa mọ, a jẹ pe won bọ ajaga kuro lọrun mi niyẹn o. Ṣugbọn bi n ko ba ni i parọ tan eeyan jẹ, ẹgbẹ PDP jẹ ẹgbẹ kan ti mo nifẹẹ si daadaa, o si wu mi pe ki n wa nibẹ titi, mi o le darapọ mọ ẹgbẹ APC rara gẹgẹ b’awọn kan ti ṣe n ro o lokan wọn bayii.