Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Bi eto idibo sipo gomina ṣe n sun mọle ni ija to wa laarin Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Agboọla Ajayi, ati ọga rẹ, Rotimi Akeredolu, n le si i.
Yatọ si ọkan-o-jọkan ẹsun tawọn mejeeji fi n kan ara wọn latẹyinwa, ọrọ ija ajadiju to wa laarin wọn lo ṣokunfa bi ẹgbẹ ZLP ti Ajayi fẹẹ ṣoju ninu eto idibo gomina to n bọ lọjọ kẹwaa, osu kẹwaa, ọdun yii, ṣe gbe ifilọlẹ eto ìpolongo wọn lọ siluu Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo, dipo ilu Akurẹ to yẹ ko ti waye gẹgẹ bii tawọn oloṣelu yooku.
Olubadamọran agba fun igbakeji gomina lori eto iroyin, Ọgbẹni Allen Ṣoworẹ, lo kọkọ fẹsun kan ijọba ipinlẹ Ondo pe ko fẹẹ yọnda ibudo ominira MKO Abiọla fun ẹgbẹ ZLP lati seto ifilọlẹ ipolongo wọn to yẹ ko waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii.
Ṣoworẹ ni iwa ika patapata ni bijọba Akeredolu ṣe ni ẹgbẹ ZLP gbọdọ san miliọnu mọkanla Naira lori ibudo naa fun ayẹyẹ ifilọlẹ ipolongo wọn, nigba to jẹ pe miliọnu marun-un Naira pere ni wọn gba lọwọ ẹgbẹ PDP to ṣe tiwọn nibi kan naa lọsẹ to kọja.
O ni oun mọ pe ṣe ni gomina mọ-ọn-mọ fẹẹ fowo nla to gbe le ibudo naa le awon sẹyin, to si ṣe bẹẹ tilẹkun ibẹ mọ Dokita Olusẹgun Mimiko to kọ ibudo ọhun lasiko to wa lori aleefa.
Lẹyin eyi lo rọ gbogbo awọn agbaagba ipinlẹ Ondo atawọn olori ẹlẹsin lati tete ba Gomina Akeredolu sọrọ lori awọn igbesẹ to lodi sijọba awa-ara-wa to n gbe lọwọ, nitori pe awọn nnkan ini ijọba ko yẹ ko wa fun ẹni kan tabi ẹgbẹ oṣelu kan soso.
Nigba to n fun wọn lesi, Olubadamọran fun gomina lori eto irinna Ọgbẹni Tobi Ogunlẹyẹ, ni ko sì ootọ rara ninu ọrọ ti ẹgbẹ ZLP n sọ.
Ogunlẹyẹ ni ki wọn lọọ wa irọ mi-in pa, nitori ko si igba ti iru idunaa-dura ti wọn n sọ yii waye laarin ẹgbẹ ZLP ati ileesẹ eto irinna ipinlẹ Ondo.
Ẹgbẹ ZLP ti ni ki i ṣe dandan ni ki awọn ṣe ifilọlẹ ipolongo ibo awọn l’Akurẹ to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo, wọn ni ori papa iṣere ijọba to wa niluu Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo, leto naa yoo ti waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii.