Adewale Adeoye
Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Dutse, nipinlẹ Jigawa, ti so pe ọdọ awọn ni ayederu dọkita kan, Ọgbẹni David Samuel wa bayii, to n ran awọn lọwọ ninu iwadii awọn, wọn ni gbara tawọn ba si ti pari iwadii naa lawọn maa foju rẹ bale-ẹjọ lori ẹsun iwa ọdaran ti awọn fi kan an.
ALAROYE gbọ pe ọwo palaba Samuel to jẹ ayederu dokita naa segi nileewosan awọn akẹkọọ kan ti wọn n pe ni ‘ Rasheed Shekoni Teaching Hospital’ to wa nijọba ibilẹ Dutse, nipinlẹ Jigawa, lakooko to n ṣe bii ojulowo dokita fawọn ti wọn wa nibẹ.
Alukoro ileeṣẹ awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọgbẹni Shiisu, ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, ni ikọ awọn ọlọpaa agbegbe naa, pẹlu atilẹyin awọn ikọ ọlọpaa DSS lọọ ṣabẹwo sile itaja igbalode kan to wa lagbegbe Mopol Base, ni Sabuwar Tukur, nijọba ibilẹ Dutse, nibi tọwọ ti tẹ ayederu dokita ọhun.
Wọn lo pẹ ti Samuel ti maa n lọọ kaakiri aarin ilu, ti yoo si maa pe ara rẹ ni dokita, to si n fi eyi lu awọn araalu ni jibiti.
Bi Samuel ṣe n lọọ ṣetọju awọn alaisan nile wọn, bẹẹ lo n ṣetọju wọn nibi gbogbo ti wọn ba ti ri i, tawọn araalu naa ko si mọ pe ayederu dokita ni ọmọkunrin naa.
Lara awọn ẹru ofin ti wọn ba lọwọ rẹ ni oniruuru iwe-ẹri to fi n sọ pe dokita loun. Lara rẹ ni iwe-ẹri pe oun jade nileewe giga Usman Danfodio University, tipinlẹ Sokoto, ati iwe ẹri pe agunbaniro to si ti sin ilẹ baba rẹ lawọn akoko kan loun. Bakan naa ni wọn tun ba ayederu iwe-ẹri pe o kẹkọọ gboye jade nipa iṣẹ iṣẹgun oyinbo nileeewe naa.
Alukoro ni loju-ẹsẹ lawọn ti fọwọ ofin mu afurasi odaran yii, o si ti jẹwọ pe loootọ loun maa n fi orukọ dọkita lu awọn araalu naa ni jibiti owo nla nigba gbogbo.
O ni ninu iwadii tawọn ṣe lawọn ti mọ pe loootọ ni Samuel ti figba kan jẹ akẹkọọ ileewe giga naa, ṣugbọn ṣe ni wọn le e jade kuro ninu ọgba ileewe naa nitori awọn ẹsun buruku kan ti wọn fi kan an.
O ni lẹyin tawọn ba ti pari iwadii tawọn n ṣe nipa rẹ lawọn maa foju rẹ bale-ẹjọ.