Aderounmu Kazeem
Bi eto idibo ipinlẹ Ondo ṣe n sunmọ etile, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu The African Democratic Congress (ADC) lapa Ila-oorun ati Iwọ-oorun Ondo ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC bayii.
Awọn eeyan wọnyi, Ọgbẹni Wale Akinlosotu ati Dokita Obama lo ko awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu yooku wọnu ẹgbẹ APC lọ. Awọn alaga wọodu ọhun mejilelogun ati awọn oloye merinlelaadọta ti wọn jẹ ọmọ ẹgbe oṣelu ADC ni wọn jọ darapọ mọ Rotimi Akeredolu ọmọ ẹgbe oṣelu APC bayii ko le jawe olubori ninu ibo to maa waye laipẹ yii.
Awọn oloye ẹgbẹ naa ti wa fi da awọn eeyan agbegbe wọn loju wi pe igbesẹ tawọn gbe yii fun ilọsiwaju ati oriire awọn eeyan agbegbe ọhun ni, ati pe digbi ni gbogbo awọn wa lẹyin Akeredolu
Enjinnia Ade Adetimẹhin lo ki wọn kaabọ sinu ẹgbẹ oṣelu APC, oun naa lo si fa wọn le Gomina Akeredolu lọwọ.
Adetimẹhin sọ pe ni bayii ti ADC ati awọn mi-in ninu ẹgbẹ ZLP ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ọhun, eyi ti fi han wi pe loke tente ni ẹgbẹ oṣelu APC wa bayii, bẹẹ ni yoo ṣoro fun ẹgbẹ kan lati jandi ẹ mọlẹ ninu ibo to n bọ.
Tẹ o ba gbagbe, ọgọọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party naa lo tẹle Ọgbẹni Boro, ati akọwe agba lẹnu iṣẹ ọba nigba kan, Adeyẹmi Adelakun wọnu ẹgbẹ oṣelu APC nibi ayẹyẹ nla kan ti wọn ṣe l’Ondo laipẹ yii.