Aderounmu Kazeem
Ẹgbẹ oṣelu APC ti ipinlẹ Edo n binu o, wọn lawọn ko gba abajade esi ibo to gbe Gomina Godwin Obaseki wọle.
Bi wọn ṣe n sọrọ ọhun niyẹn o, bo tilẹ jẹ pe gbogbo aye lo so pe eto idibo ọhun lọ daadaa, ti Aarẹ Muhammed Buhari paapaa si ti tẹwọ gba a, to tun ti ki Obaseki ku oriire.
Bo tilẹ jẹ pe wọn lawọn ko gba, sibẹ wọn ti rọ awọn ọmọ ẹgbe wọn nipinlẹ Edo lati ṣe jẹjẹ, ki wọn ma fa wahala kankan.
Ninu ọrọ ti alaga feto iroyin ipolongo ibo APC l’Edo, Ọgbẹni John Mayaki, sọ, o ni ẹgbẹ oṣelu naa ko gba abajade esi ibo ọhun rara.
Lara ẹsun to ka ni pe niṣe ni wọn ko awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun da satimọle, ati pe awọn esi ibo ti PDP ṣe arọdarọda ẹ lo pọju. O ni pupọ ninu awọn agbegbe tawọn ti jawe olubori ni wọn fagile esi ibo ibẹ
O ni, “Wọn fagile esi ibo tiwa lawọn ibi ta a ti ṣe daadaa, bẹẹ ni wọn fi eru kọ ibo rẹpẹtẹ funra wọn, fun idi eyi, awa ko gba esi ibo ọhun rara, ojooro ni ẹgbẹ oṣelu PDP fi jawe olubori.” Mayaki lo sọ bẹẹ.
Ṣa o, Pasitọ Ize Iyamu ni tiẹ ti dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Edo bẹẹ gegẹ lo ti ki Obaseki ku oriire, ṣugbọn oun naa ti sọ pe oun ṣi n ṣayẹwo abajade esi ibo ọhun, ko si ni i pẹ ti oun yoo jẹ ki awọn eeyan mọ igbesẹ ti oun funra oun maa gbe.