Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Oludamọran pataki fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Sẹnetọ Babafẹmi Ojudu, ọkọ ọmọ Aṣiwaju Bọla Tinubu, Ọnarebu Oyetunde Ojo, atawọn mi-in ti yari mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) nipinlẹ Ekiti lọwọ lori ẹjọ ti wọn ni ki wọn waa ro.
Awọn to ku ni Dokita Wọle Oluyẹde, Enjinnia Ayọ Ajibade, Ọnarebu Fẹmi Adelẹyẹ, Bunmi Ogunlẹyẹ, Akin Akọmọlafẹ, Bamigboye Adegoroye, Oluṣọga Owoẹyẹ, Dele Afọlabi, Toyin Oluwaṣọla ati Ben Oguntuaṣe.
Igbesẹ naa waye lẹyin bii ọsẹ kan ti ẹgbẹ APC l’Ekiti kede pe ki igbimọ ẹlẹni-mẹjọ kan ṣeto bi wọn yoo ṣe fun awọn eeyan ọhun niwee gbele-ẹ lẹyin ti wọn ba sọ tẹnu wọn latari ẹjọ ti wọn n ba ẹgbẹ ṣe nile-ẹjọ giga ilu Ado-Ekiti.
Adari ẹka iroyin ẹgbẹ naa, Alagba Sam Oluwalana, ṣalaye pe igbesẹ kootu tawọn eeyan naa gbe ni ẹgbẹ fi fẹẹ gbe igbesẹ tiẹ.
Ojudu atawọn mọkanla to ku lo gbe Amofin Paul Ọmọtọshọ to jẹ alaga APC l’Ekiti atawọn ọmọ igbimọ alaṣe to ku lọ si kootu lori ẹtọ ti wọn ni lati jẹ adari ẹgbẹ.
Ninu lẹta tawọn eeyan naa ṣẹṣẹ kọ bayii nipasẹ lọọya wọn, Oloye Ademiyiwa Adeniyi, wọn ni awọn ko ni i wa siwaju igbimọ oluwadii kankan nitori oju aye lasan ni wọn fẹẹ ṣe, ọrọ ti wọn sọ si ti fi han pe ootọ kankan ko le jẹ yọ ninu abajade wọn.
Wọn ni ko si ootọ ninu pe awọn adari ẹgbẹ patapata lo ran wọn niṣẹ, nitori awọn lẹtọọ lati lọ si kootu ti wọn ba yan awọn jẹ, ati pe Oluwalana tiẹ ti sọ iṣẹ ti igbimọ naa fẹẹ ṣe.
Bakan naa ni wọn ni ibudo ti wọn fipade si jẹ otẹẹli ti Ọmọtọshọ da silẹ, bẹẹ o wa lara awọn tawọn pe lẹjọ.
Wọn waa ni awọn ti gbiyanju lati pari ọrọ naa nitubi-inubi, ṣugbọn ti ko si ọna abayọ, eyi lo jẹ kawọn gba kootu lọ, awọn si tun ṣetan lati pari ija fun ilọsiwaju ati irẹpọ ninu ẹgbẹ.