Stephen Ajagbe, Ilorin
Ajọ kan to n ja fun ominira awọn ijọba ibilẹ lorilẹede Naijiria, Coalition of Civi Society on Autonomy of Local Goverment in Nigeria, ti ni Gomina Abdulrahman Abdulrazaq tipinlẹ Kwara gbọdọ ṣalaye bo ṣe ṣe biliọnu mọkanlelogoji owo to ti wọle sapo ijọba ibilẹ lati oṣu mẹrindinlogun sẹyin, ko si tun ṣeto idibo abẹle.
Adari ajọ naa, Mallam Musa Aliu, to sọrọ ọhun nibi ipade awọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọside, ni o yẹ ki gomina ti gbe ajọ ẹleto idibo ipinlẹ, KWASIEC, kalẹ, lati ṣeto idibo kansu, o pẹ ju, oṣu kejila, ọdun yii.
O ni igbesẹ ti gomina naa n gbe ko fi han pe o ṣetan lati ṣeto idibo ijọba ibilẹ rara, nitori pe latigba to ti de ori ipo lo ti le awọn to n sakoso kansu danu, awọn oṣiṣẹ ijọba to wa nipo giga lo n lo. Eyi ni Aliu ni o tako ofin to de isakoso ijọba ibilẹ lorilẹede Naijiria.
Mallam Aliu ni, “Lati oṣu karun-un, ọdun 2019, titi de oṣu kẹsan-an, ọdun 2020, owo to ti wọle sapo ijọba ibilẹ ti le ni biliọnu mọkanlelogoji naira, #41,251,620,745.68. Gomina Abdulrazaq gbọdọ ṣalaye fun gbogbo araalu bi wọn ṣe lo owo naa.
“To ba si kọ lati ṣe bẹẹ, awọn eeyan, bii tiwa bayii, yoo gba ile-ẹjọ lọ, lati kan an nipa fun un lati ṣalaye bi owo awọn ijọba ibilẹ mẹrindinlogun naa ṣe rin. Ẹtọ Gomina ni lati jẹ ki araalu mọ bo ṣe n na owo wọn.
O ni ofin ti la kalẹ pe gomina ni lati gbe igbimọ ti yoo ṣeto idibo sijọba ibilẹ kalẹ, o pẹ ju, laarin oṣu kọkanla, ọdun yii. Bakan naa, ẹni to ba maa jẹ alaga KWASIEC ko gbọdọ jẹ oloṣelu tabi ọmọ ẹgbẹ oṣelu kankan.
O ṣalaye pe ko ni i bofin mu fun gomina lati gbe igbimọ alaamojuto kalẹ lati maa sakoso ijọba ibilẹ tabi ko maa lo awọn oṣiṣẹ ijọba.