Aderounmu Kazeem
Lẹyin wakati bii meloo kan tawọn ọdọ ya bo ibi ti ijọba ko awọn ounjẹ iranwọ si lagbegbe Mazamaza l’Ekoo, wọn ni wọn tun ti ya bo ibomi-in bayii o.
Agbegbe kan to n jẹ Agric ni Ọjọ lojuna Eko si Badagry ni wọn sọ pe awọn eeyan kan tun ya lọ bayii, nibi ti wọn ti lọọ n ko ounjẹ, ti ijọba ko pamọ lati fi ran awọn araalu lọwọ lasiko isemọle ajakalẹ arun koronafairọọsi.
Kẹtikẹti ni wọn n ko oriṣiiriiṣi ounjẹ bii gaari, indomie, suga, iyọ, ẹwa atawọn ounjẹ mi-in loriiṣiriiṣi, tawọn ti ko gbọ nipa e tẹlẹ paapaa n sare lọọ ko tiwọn.