Faith Adebọla
Olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja, Fẹmi Gbajabiamila, ti ṣabẹwo si Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, latari rogbodiyan to ṣẹlẹ nipinlẹ naa, nibi ti ọpọ dukia ijọba ti jona guruguru.
O fi aidunnu rẹ han si iṣẹlẹ naa, bẹẹ lo si ba gomina atawọn eeyan ipinlẹ Eko kẹdun.
Sanwo-olu mu olori awọn aṣoju-sofin to wa l’Abuja naa kaakiri awọn dukia ijọba ti wọn bajẹ.
Bakan naa ni ọkunrin yii ṣabẹwo ibanukẹdun si Ọba ilu Eko, Rilwan Akiolu, lati ba a kẹdun bi wọn ṣe ba afin rẹ jẹ lasiko rogbodiyan to waye lẹyin tawọn ṣọja loọ yinbọn fun awọn ọdọ kan to kora jọ pọ sibi ti wọn ti n ṣe iwọde ni Lẹkki.
Bẹẹ lo fẹsẹ kan de ọdọ Asiwaju Tinubu naa.
Lasiko abẹwo yii lo ṣeleri iranlọwọ awọn aṣofin fun ipinlẹ Eko. O ni awọn yoo nawọ iranlọwọ si wọn ati awọn ipinlẹ mi-in ti wahala yii ti ṣẹlẹ ti awọn ba ti wọle ijokoo pada.