Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti, labẹ idari CP Tunde Mobayọ, ti bẹrẹ iwadii ijinlẹ lati mọ awọn to pa ọdọmọde oniṣowo kan, Ọlanrewaju Ọladapọ, niluu Ado-Ekiti l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Oloogbe naa lawọn agbebọn kan da ẹmi ẹ legbodo ni nnkan bii aago mẹwaa ku iṣẹju mẹẹẹdogun alẹ ọjọ naa nile ẹ to wa lagbegbe Dallimore, l’Ado-Ekiti.
Ẹnikan to n gbe lagbegbe tiṣẹlẹ ọhun ti waye sọ fun ALAROYE pe agbegbe ọhun naa ni Ọlanrewaju ti n ta kaadi ipe atawọn nnkan jijẹ, bo si ṣe kuro ni ṣọọbu ẹ lo kọri sile. O ni awọn agbebọn naa tẹle e de ile ẹ to wa lẹyin ileewosan kan lagbegbe ọhun, ẹnu ọna gan-an ni wọn si pa a si.
Lẹyin eyi lo ni wọn ko owo atawọn nnkan ini ẹ mi-in ki wọn too ba tiwọn lọ.
Akọroyin wa gbọ pe oṣu diẹ sẹyin ni oloogbe naa ko de ibi ti wọn pa a si yii, iru iṣẹlẹ bẹẹ lo si n sa fun to fi ko wa si agbegbe naa, ṣugbọn o jọ pe awọn to n le e kiri naa lo pada da ẹmi ẹ legbodo.
Ọdọmọde oniṣowo to jara mọ’ṣẹ ni wọn pe Ọlanrewaju nigba aye ẹ, bẹẹ lo jẹ ẹni to bọwọ fun eeyan, ki i ṣe oniwahala rara.
Ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti, nipasẹ ASP Sunday Abutu to jẹ Alukoro wọn, ti sọ pe awọn n ṣewadii iṣẹlẹ ọhun lọwọ, awọn si n wa awọn amookunṣika ọhun.
Lasiko ta a pari akojọpọ iroyin yii, mọṣuari ni oku oloogbe wa.