Jide Alabi
Nibi ipade ti Aarẹ orilẹ-ede yii, Muhammadu Buhari, ṣe pẹlu awọn ọba alaye kan ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii lo ti ran wọn niṣẹ si gbogbo ọdọ agbegbe wọn.
Sultan ilu Sokoto, Ọba Sa’ad Abubakar, lo ko awọn ọba alaye ọhun sodi lọọ ba Buhari, ṣepade.
Ninu atẹjade ti Oludamọra Aarẹ lori eto iroyin, Fẹmi Adeṣina, fi sita lorukọ Aarẹ Muahmmadu Buhari lo ti ṣalaye gbogbo ohun ti ipade ọhun da le lori. O ni koko ohun ti wọn fi pe ipade ọhun ni bi awọn ọba alaye yoo ṣe ba awọn ọdọ agbegbe wọn sọrọ, ti alaafia yoo ṣe wa laarin ilu, ti rogbodiyan iwọde atawọn nnkan to le da ilu ru ko fi ni i waye mọ.
Aarẹ Muhammadu Buhari sọ pe gbogbo ohun ti awọn ọdọ sọ pata loun ti gbọ, bẹẹ loun gbọ ọ lagbọye pẹlu, ṣugbọn ki wọn fun ijọba oun lanfaani lati ṣatunṣe si gbogbo ohun ti wọn pakiyesi ijọba oun si.
O ni, “Ẹyin ọba alaye ni ipa nla ti ẹ maa ko ninu ọrọ to delẹ yii, nitori ẹyin gan-an naa lẹ sun mọ awọn araalu ju lọ. Bakan naa ni mo ki yin fun ipa ribiribi tẹ ẹ ko lati ba awọn ọdọ agbegbe yin sọrọ, ti wọn fi sinmi ogun.”
Lara ohun ti ijọba loun ni lọkan bayii ni igbimọ kan to sọ pe oun yoo gbe dide, ti yoo lọ kaakiri ọdọ awọn ̀ọba alaye, eyi ti olori awọn oṣiṣẹ Aarẹ, Ibarhim Gambari, yoo jẹ olori ẹ, ti yoo si maa waa ja bọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari.
Aarẹ, ko sai sọ pe ijọba oun ko ni i faaye gba ẹnikẹni lati huwa idaluru, tabi di oun lọwọ lori atunṣe ti oun fẹẹ ṣe lori gbogbo ohun ti awọn ọdọ lawọn fẹ.