Jide Alabi
Ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọyọ, ti rọ gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ọgbẹni Peter Ayọdele Fayoṣe, lati fi Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde lọrun silẹ, ko jẹ ko lo ipo ẹ gẹgẹ bii aṣaaju ẹgbẹ naa ni ilẹ Yoruba.
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọyọ, Akeem Olatunji, sọ pe ni gbogbo asiko ti Fayoṣe fi wa nipo gomina l’Ekiti, to jẹ oun nikan ṣoṣo ni gomina ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP to wa nilẹ Yoruba, ko sẹni to yọ ọ lẹnu, bẹẹ lo lo ipo olori fun ẹgbẹ naa lai si idiwọ kankan gẹgẹ bi ofin PDP ṣe la a silẹ.
Ọkunrin naa ni idaamu ti Fayoṣe fẹẹ maa ko ba Gomina Ṣeyi Makinde yii ki i ṣe ohun to tọna rara, nitori pe oun naa ti lo iru ipo ọhun ri, ohun to si ṣe pataki ni pe ko jẹ ki ẹni to kan bayii naa ri igba tiẹ lo gẹgẹ bii gomina kan ṣoṣo ti PDP ni nilẹ Yoruba.
O ni lasiko ti Fayoṣe wa nipo, oun yii lo yan awọn oloye egbẹ fun ẹka gbogbogboo ati ti ipinlẹ, ti ẹnikankan ko si ba a fa wahala rara lori ipinnu ẹ.
Ohun to fa ọrọ ti Ọlatunji sọ yii ko ṣai da lori igbesẹ ti gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ ọhun gbe lori bo ṣe tun lọọ yan awọn ọmọ igbimọ PDP mi-in fun gbogbo ilẹ Yoruba lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, lẹyin ti Gomina Ṣeyi Makinde, ti ṣe bẹẹ tẹlẹ.
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọyọ yii sọ pe ṣaaju igbimọ ti Peter Ayọdele Fayoṣe tun yan fawọn ipinlẹ wọnyi; Ọyọ, Eko, Ọṣun, Ondo, Ekiti ati ipinlẹ Ogun ni Gomina Ṣeyi Makinde ti yan irufẹ igbimọ ọhun nile ijọba ipinlẹ ̀Ọyọ. O ni o ṣe e ni ibamu pẹlu ipo ẹ gẹgẹ bii aṣiwaju ẹgbẹ naa, nitori ipo ẹ gẹgẹ bii gomina kan ṣoṣo ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni nilẹ Yoruba.
O fi kun un pe ohun to da oun loju ni pe ko si wahala kankan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, ati pe igbagbọ ti ẹgbẹ naa ni ninu Gomina Ṣeyi Makinde gẹgẹ bii aṣiwaju ẹgbẹ naa ko yingin rara.
Bakan naa lo sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, ẹka ipinlẹ Ọyọ, ti wọn tun lọọ jokoo pẹlu awọn Fayoṣe lọ sibẹ lorukọ ara wọn ni, ki i ṣe ẹgbẹ oṣelu PDP Ọyọ ni wọn lọọ ṣoju fun.
O pẹ ti iṣoro ẹni to yẹ ko maa dari ẹgbẹ oṣelu PDP lawọn ipinlẹ ilẹ Yoruba ti wa laarin Fayoṣe ati Ṣeyi Makinde. Awọn alaga ẹgbẹ ọhun lawọn ipinlẹ mẹrin ninu mẹfa ni wọn n tẹle Fayoṣe kiri, nigba ti meji pere n ṣe ti Ṣeyi Makinde.
Alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ondo ati Ọyọ ni wọn n ṣe ti Ṣeyi Makinde, nigba ti alaga ẹgbẹ naa ni Eko, Ekiti, Ogun ati Ọṣun si ba Fayoṣe lọ.
Ko gbọdọ sí irú igbalaye yẹn rara.
Won tun fẹ dá egbé sí méjì nìyẹn.
Wọn fẹ dàrú bi omisore ṣẹṣẹ ni 2018 losun to fi da ibo osun ru nìyẹn.