Faith Adebọla, Eko
Adugbo kan ti wọn n pe ni Orita, ni Igbo Agbọwa, lagbegbe Ikorodu, lawọn ọkunrin mẹta kan, gbe ẹbọ lọ, afi bawọn araalu ṣe ka wọn mọbẹ, ni wọn ba fagidi mu wọn pe dandan ni ki wọn ko ẹbọ ati etutu ti wọn fẹẹ gbe kalẹ jẹ funra wọn lọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii.
Boya ka ni alẹ tawọn babalawo saaba maa n gbe ẹbọ ni wọn dan kinni ọhun wo ni, ọrọ ko ni i ri bo ṣe ri yii, ṣugbọn ọsan gangan lawọn ọkunrin mẹta naa gbe ẹbọ ọhun, ti ẹnikan n lọ niwaju, tawọn meji si n tẹle e.
A gbọ pe bo ṣe ku diẹ ki wọn gbe ẹbọ naa kalẹ lorita yii lawọn ọdọ adugbo atawọn agbaagba ti wọn ti n ṣọ wọn ba pariwo ‘agbedọ!
Bayii lo ṣe di pe awọn ọdọ ilu yi wọn po, ti wọn si ni ki awọn funra wọn bẹrẹ si i ko ẹbọ ti wọn fẹẹ gbe kalẹ naa jẹ kiakia.
Wọn lawọn to gb’ẹbọ ọhun tiẹ kọkọ fẹẹ ṣagidi, eyi lo si mu kawọn ọdọ naa fi apola igi, okuta ati paṣan din dundu iya fun wọn. Ẹyin ti wọn da sẹria fun wọn tan ni wọn tun fipa mu wọn lati ko ẹbọ ti wọn gbe wa jẹ, ajẹ-pọn-ọwọ-la ni wọn jẹ’bọ ọhun, tori oju ina kọ ni ewura n hu irun.
Wọn ni arọwa ati ẹbẹ awọn ọkunrin naa to pọ lẹyin ti wọn ti k’ẹbọ wọn jẹ tan ni ko jẹ ki wọn wọ wọn lọ si teṣan ọlọpaa, ti wọn fi ni ki wọn fọwọ fa eti wọn.
Boya ẹbọ waa fin tabi ko fin o, awọn ẹlẹbọ naa lo le sọ, iyẹn ti wọn ba pada lọọ sọ ohun toju wọn ri fun babalawo wọn.