Johnson kọ iyawo ẹ n’Ibadan, o ni pasitọ ati alagba ijọ n ba a laṣepọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Agbere ṣiṣe ti da idile Onigbagbọ ru n’Ibadan, ọkọ iyawo, Johson Olumuyiwa, fẹsun agbere kan iyawo ẹ to n jẹ Ọmọtayọ, o ni pasitọ ati alagba ijọ awọn, Ọmọtayọ Olumuyiwa, n yan lale, gbogbo igba lawọn ojiṣẹ Ọlọrun naa si ti ba a laṣepọ karakara.

Igbimọ awọn adajọ kootu ibilẹ Ọja’ba to wa laduugbo Mapo, n’Ibadan, ti fopin si igbeyawo ọlọdun mẹrinlelogun ọhun.

Ninu awijare ẹ niwaju igbimọ awọn adajọ, Johnson sọ pe diẹ lo ku ki iyawo oun pa oun danu pẹlu bo ṣe yọ ọbẹ si oun laarin oru lọjọ kan, ṣugbọn to jẹ pe Ọlọrun ni ko fi ẹmi oun le e lọwọ.

Ọkunrin olugbe adugbo Ẹlẹta, n’Ibadan, yii sọ pe o pẹ tawọn eeyan ti maa n sọ foun nipa bi alufaa ijọ awọn pẹlu pasitọ ṣọọṣi awọn ṣe maa n ba iyawo oun laṣepọ, ṣugbọn ti oun ko ka a kun, afigba ti aṣiri wọn tu si oun funra oun lọwọ.

“Gbogbo igba lo maa n tẹnu mọ ọn pe ki n maa lọọ gbadura fun idande ati itusilẹ lọdọ alufaa ati alagba ijọ wa. Emi naa si maa n lọ sọdọ wọn, afigba ti mo ri i pe awọn mejeeji n laṣepọ pẹlu iyawo mi loootọ. Bẹẹ awọn eeyan yii ni wọn maa n waa pari ija fun wa ni gbogbo igba ta a ba ni gbolohun asọ o”, bẹẹ lolupẹjọ sọ.

“Ifẹ ikọkọ to wa laarin iyawo mi atawọn to n yan an lale yii lo fa a to ṣe fẹẹ pa mi. Laarin oru ọjọ kan lo yọ ọbẹ si mi. Ọlọrun lo ni ki n tete ri i, ki n si gba a lọwọ ẹ, boya ọjọ yẹn ni nba raye mọ.”

Johnson ni latigba ti aṣiri yii ti tu soun lọwọ loun ti pa ṣọọṣi naa ti nitori oun ko le maa jọsin ninu ijọ awọn alagbere  ni toun.

O waa rọ ile-ẹjọ lati fopin si ibaṣepọ oun atiyawo ẹ gẹgẹ bii tọkọ-taya.

Ọmọtayọ ko si nile-ẹjọ lati sọ awijare ẹ, akọda kootu ọhun sọ pe ẹẹmẹta ọtọọtọ loun ti mu iwe ipẹjọ lọọ ba obinrin naa nile, o kan mọ-ọn-mọ dagunla sile-ẹjọ ni.

Olori igbimọ awọn adajọ kootu naa, Oloye Ọdunade Ademọla, ti tu igbeyawo oọdun mẹrinlelogun ọhun ka. Niwọn igba to jẹ pe olupẹjọ lo ti n da tọju awọn ọmọ naa tẹlẹ, ọkunrin naa nile-ẹjọ yọnda ọmọ mejeeji to wa laarin wọn fun.

 

Leave a Reply