Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ẹgbẹ oṣelu APC yii ti kede orukọ awọn to kunju oṣuwọn ati kopa ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ naa to n bọ nipinlẹ Ondo logunjọ, osu keje, ọdun ta a wa yii.
Igbakeji akọwe ipolongo ẹgbẹ naa lorilẹ-ede yii, Ọgbẹni Yẹkini Nabẹna, lo fidi ọrọ naa mulẹ ninu atẹjade to fi sita lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii.
O ni gbogbo awọn oludije mejila to gba fọomu ati dije lasiko eto ibo abẹle naa ni wọn yege ninu ayẹwo ati ifọrọwerọ ti wọn ṣe fun wọn l’Abuja lọsẹ to kọja.
Eyi lawọn oludije ọhun gẹgẹ bo ṣe to wọn lẹsẹẹsẹ, Amofin agba Oluwarotimi Ọdunayọ Akeredolu, Joseph Oluṣọla Iji, Odimayọ Okunjẹmi John, Ọlayide Owolabi Adelami ati Kekemeke Duerimini Isaac.
Awọn mi-in to tun darukọ ni, Amofin agba Oluṣọla Oke Alex, Ifẹoluwa Oluṣọla Oyedele, Ọlajumọkẹ Olubusọla Anifowoṣe, Awodeyi Akinsẹhinwa Akinọla, Adetula Olubukọla Ọlarọgba, Dokita Abraham Olusẹgun ati Dokita Nathaniel O.Adejutelẹgan.
Nabẹna sọ ninu ọrọ rẹ pe awọn oluṣayẹwo ọhun ti fi abajade wọn sọwọ si alaga afunsọ ẹgbẹ APC, Alaaji Mai Mala Buni, ti i ṣe gomina ipinlẹ Yobe.
Ohun kan soso to ku tawon eeyan n reti bayii lati ọdọ awọn asaaju ẹgbẹ APC ni ki wọn kede ọna ti wọn fẹẹ fi ṣeto ibo abẹle to n bọ lọna ọhun.