Jide Alabi
Olori ijọ Ridiimu, Pasitọ Enoch Adeboye, ti fi awọn ọmọ Naijiria lọkan balẹ pe owo naira yoo tun lagbara si i laipẹ yii.
Nibi ipade ọlọdọọdun ti ijọ naa maa n ṣe, eyi to waye ni gbọngan nla ileejọsin ijọ naa ni Adeboye ti sọrọ yii laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, pe Ọlọrun yoo ko si awọn to wa nipo aṣẹ ninu lori bi wọn ṣe n din agba naira ku si dọla, ti owo Naijiria yoo si tun lagbara daadaa pada laipẹ ọjọ.
Ninu ọrọ Adeboye naa lo ti sọ pe ni aimọye ọdun sẹyin ti oun pe awọn eeyan sibi ipagọ, ti oun si ṣeleri jijẹ mimu fun wọn lọfẹẹ, ṣugbọn nigba to dọwọ aarọ ni iyawo oun waa ba oun pe oun nilo ẹgbẹrun marun-un naira lati fi ṣe nnkan kan, ṣugbọn ti oun ko ni owo kankan lọwọ lọjọ naa. Adeboye sọ pe owo nla ni ẹgbẹrun naira marun-un nigba yẹn, bẹẹ ni ko si kọbọ lọwọ oun tabi ọna abayọ kankan afi Ọlọrun Ọba.
Pẹlu igbagbọ ni Adeboye sọ pe oun fi ke pe Ọlọrun, ti ẹnikan ti ki i ṣe ọmọ ijọ naa wọle wa, to si loun naa fi owo nla da si eto ti awọn n ṣe lọjọ naa.
Olori ijọ Ridiimu yii ti sọ pe Ọlọrun to ṣiṣẹ iyanu ọhun lọjọ naa lọhun-un ṣi wa nipo agbara, oun si nikan naa lo le gba Naijiria silẹ lọwọ bi naira ṣe ri yii, ti ohun gbogbo fi wọn bii oju lorilẹ-ede wa.
Ni bayii, iye ti wọn n ta dọla kan si owo naira Naijiria ti di ẹẹdẹgbẹta naira si naira mọkandinlẹẹẹdẹgbẹta, bo tilẹ jẹ pe ọọdunrun naira ati naira mọkandinlọgọrin (N379) lo wa lori ikanni ayelujara banki apapọ ilẹ wa, iyẹn Central Bank, gẹgẹ bii owo ti wọn n ta a, ti wọn tun n ra a.