Aderounmu Kazeem
Aarẹ Orilẹ-ede yii, Muhammadu Buhari, tun ri ibinu awon ọmo Naijiria nigbai ti fidio jade pe baba naa bẹ oko rẹ to wa ni Daura wo lati lọọ ri awọn maalu rẹ ati awọn nnkan ọsin mi-in to ni sibẹ. Ohun to bi awọn ọmo Naijiria ninu si i ree, nitori ko de ibi ti iṣẹlẹ awọnti won ji awon ọmọleewe gbe ti waye, n lawon eeyan ba n beere pe bawo leeyan yo kuku ṣe daju to bayii, tabi baba naa ki i ṣe abiyamọ ni.
Loootọ, Garba Shehu sọ pe ki iroyin iṣẹlẹ buruku naa to de eti Buhari lo ti lọ sinu oko rẹ, ṣugbọn ko sẹni to gba a gbọ, nitori lalẹ ọjọ ti Buhari de Daura ni wọn ji awọn ọmọ yii ko, ilẹ ko si ti i mọ rara ti iroyin idagiri naa ti gba gbogbo aye kan. Bawo ni Aarẹ Naijiria ko ṣe waa ni i gbọ iru iroyin bẹẹ.
Koda, awọn eeyan kan lagbegbe ti iṣẹlẹ buruku yii ti waye fidi ẹ mulẹ wi pe ni kete ti wọn ji awọn ọmọ ọhun ko, abule kan lẹgbẹẹ ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ni wọn kọkọ ko wọn lọ, ki wọn too ko wọn lọ si ibuba wọn bayii.
Awọn ọmọleewe bii ọdunrun ati mẹtalelọgbọn (333) ni wọn sọ pe wọn ṣi wa lọwọ awọn ajinigbe ọhun.
Bo tilẹ jẹ pe ilu Kankara tiṣẹlẹ ọhun ti waye, ti ko ju bii maili marundinlaadoje (125) si ilu Daura, ti i ṣe ilu abinibi Buhari ni Katsina, bi Aarẹ ko ṣe yọju si wọn nibẹ yẹn n dun awọn eeyan orilẹ-ede yii gidigidi, bẹẹ ni wọn n sọ pe yatọ si pe o jẹ aarẹ orilẹ-ede, abiyamọ kan to ba ni itara ọmọ ko gbọdọ ṣe bẹẹ lawujọ awọn eeyan gidi.
Ni bayii, awọn eeyan agbegbe ti wahala ̀ọhun ti ṣẹlẹ ti n jade ṣalaye bo ti ṣe waye gan-an. Ọkunrin kan to ni ki awọn oniroyin forukọ bo oun laṣiiri sọ pe, ilu kan ti wọn n pe ni Puwa lawọn janduku ọhun kọkọ de si lọwọ aarọ bii aago mọkanla lọjọ Ẹti, Furaidee.
O ni lọwọ ọsan lawọn kan ninu wọn gun ọkada wọn lọ si Kankara lati lọ wo bii eto aabo ibẹ ṣe gbopọn si. O ni lọwọ aṣalẹ lẹyin tawọn ọmọleewe ti jẹun tan, ti kaluku n mura lati lọọ sun ni wọn ya bo wọn, ti wọn si ko wọn lọpọ yanturu sori ọkada ti wọn gbe lọ ka wọn mọ.
Ẹni to sọrọ yii sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe nitori ti wọn pa awọn Fulani kan lagbegbe ọhun tẹlẹ lo ṣokunfa ikọlu yii.