Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ijọba ipinlẹ Ondo ti fofin de aisun tabi isọ-oru lasiko ayẹyẹ Keresimesi ati ọdun tuntun to n bọ lọna, gbogbo eto awọn ile ìjọsìn wọnyi ni wọn ni ko gbọdọ kọja aago mẹwaa alẹ titi tọrọ arun Korona to tun gbode bayii yoo fi kasẹ nilẹ.
Bakan naa nijọba tun fi ọsẹ meji gbako kun ọjọ tawọn akẹkọọ ipinlẹ naa fẹẹ wọle fun saa eto ẹkọ tuntun.
Iwọle awọn ọmọ ileewe ni wọn ti sun si ọjọ kejidinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ, dipo ọjọ kẹrin ti wọn kọkọ fi si.
Alaga igbimọ to n ri si didena itankalẹ arun Korona nipinlẹ Ondo, Ọjọgbọn Olusẹgun Fatusin, sọ fawọn araalu l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni ọkan-o-jọkan ipade loun ti ṣe pẹlu awọn ti ọrọ kan lori ọna ti wọn fi le tete dena ajakalẹ arun naa ko too tun tan kalẹ kọja bo ṣe yẹ.
Ọga agba fasiti Imọ Iṣegun to wa niluu Ondo ọhun ni ki i ṣe awọn ile-ijosin nikan lofin tuntun naa ba wi, gbogbo awọn ile-ijo, ile-ọti ati ibi igbafẹ ni wọn gbọdọ ti pa ni kete ti aago mẹwaa alẹ ba ti lu.
O ni ki ẹnikẹni tọwọ ba tẹ pe o ṣẹ sofin ati ilana tijọba fi lelẹ lori ọrọ arun Korona maa mura lati fẹwọn oṣu mẹta jura tabi ki iru ẹni bẹẹ san ẹgbẹrun lọna ogun Naira gẹgẹ bii owo itanran.