Ọlawale Ajao, Ibadan
Eeyan mẹrin lawọn ọmọ iṣọta ti pa danu lagbegbe Ìjokòdó, n’Ibadan, laarin ọsẹ meji sẹyin.
Eyi lo fa a to fi jẹ pe inu ibẹrubojo lọpọ awọn olugbe adugbo naa wa lọwọlọwọ bayii, awọn kan ninu wọn paapaa ko si to ẹru ti i sun inu ile wọn mọ.
Olugbe adugbo Ijokodo kan to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe lati bii ọsẹ meji sẹyin lawọn tọọgi ti gbakoso agbegbe naa, o si kere tan, eeyan mẹrin ni wọn ti pa nipasẹ ibọn ati ada.
Gege bo ṣe sọ, “Ojoojumọ lawọn tọọgi n ṣọṣẹ laduugbo wa lẹnu ọjọ mẹta yii. Lọsẹ to kọja, ẹẹmẹta niyawo mi pe mi pe ki n ma wulẹ wale o, ki n sun si ṣọọbu nitori adugbo ti daru o.”
Ọkunrin ti ko fẹ ka darukọ oun yii waa fi aidunnu ẹ han si bi ijọba ipinlẹ Ọyọ ko ṣe ri nnkan kan ṣe si ọrọ eto aabo to ti mẹhẹ yii.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni awọn ọlọpaa ti gbakoso eto aabo agbegbe naa, ati pe ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ yii, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, ti ṣe akanṣe eto lati jẹ ki eto aabo tubọ gbopọn si i jake-jado ipinlẹ naa.
Gbogbo ikọ eleto aabo to wa ni ipinlẹ Ọyọ bii Operation Burst, OPC ati Amọtẹkun ni wọn duro si ikorita Ijokodo bayii lati ri i pe awọn janduku ko gbérí mọ lagbegbe naa.