Florence Babaṣọla
Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Wale Ọlọkọde, ti ṣafihan mẹta lara awọn tọọgi to da wahala silẹ laaarin awọn ẹya Yoruba ati Hausa niluu Oṣogbo laipẹ yii.
Awọn mẹtẹẹta ni Aderẹmi Serif, ti gbogbo eeyan mọ si Sungbengbe, ẹni ọdun mejilelọgbọn, Lawal Dauda, ẹni ogun ọdun, ati Bello Taofeek toun jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun.
Ọlọkọde ṣalaye pe nirọlẹ ọjọ Keresimesi ku ọla, iyẹn ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kejila, ọdun to kọja, lawọn ọdọ kan ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Ikiọla Group kora wọn jọ, ti wọn si lawọn n tan abẹla fun ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ awọn to jade laye.
Lasiko ti wọn de agbegbe Sabo, niluu Oṣogbo, lawọn kan lara wọn ti kọju ija si awọn Hausa meji ti wọn n ta tii (tea) ati suya. Wọn ji suya, owo, bẹẹ ni wọn ba kireeti ẹyin mẹwaa jẹ nibẹ.
Ibi ti wahala ti bẹrẹ niyi, eleyii to si yọri si iku Hausa kan; Zakariyahu Abdulahi, nigba ti ọpọlọpọ eeyan fara pa ko too di pe awọn ọlọpaa ṣeto alaafia pada sagbegbe naa.
O ṣalaye pe awọn mẹtẹẹta ti ọwọ tẹ ti n ran awọn ọlọpaa lọwọ ninu iwadii wọn, idaniloju si wa pe laipẹ ni ọwọ yoo tun tẹ lara awọn ọmọ ganfe naa ti wọn ti sọ agbegbe Sabo ati ilu Oṣogbo lapapọ di ibugbe ẹru fawọn araalu.
Kọmisanna yii kilọ pe wiwa oun si Ọṣun ki i ṣe pẹlu ọwọ yẹpẹrẹ rara, o ni ikoko oun ko ni i gba omi, ko tun gba ẹyin fun awọn janduku nibikibi ti wọn ba fara pamọ si.