Faith Adebọla
O kere tan, ogun (20) lara awọn olori ileegbimọ aṣofin tẹlẹ ri atawọn to ṣi wa nipo lawọn ipinlẹ Iwọ-Oorun ni wọn kora jọ si ipade pataki kan to waye niluu Ibadan lọsẹ yii, pataki ipade naa ni lati jiroro bi wọn ṣe maa ṣan ọna fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lati di aarẹ Naijiria ninu eto idibo gbogbogboo to maa waye lọdun 2023.
ALAROYE gbọ pe ọjọ meji gbako nipade naa fi waye, lati Ọjọbọ, Wesidee, si Ọjọruu, Tọsidee, ọsẹ yii, ni otẹẹli Carlton Gate Xclusive, to wa ni ọna Total Garden, l’Agodi, GRA niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.
Ọkan pataki ninu awọn to sọrọ nipade ọhun ni Olori awọn aṣofin ipinlẹ Eko, Ọnarebu Mudaṣhiru Ọbasa, oun ni wọn lo ṣefilọlẹ ẹgbẹ tuntun kan ti wọn pe ni Bọla Ahmed Tinubu Foundation and Movement, BAT Foundation.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ete pataki ti ẹgbẹ naa wa fun ni lati gbogun ti iṣẹ ati oṣi nilẹ wa, ki wọn polongo, ki wọn si jẹ kawọn eeyan mọyi bi Aṣaaju apapọ fun ẹgbẹ APC, Bọla Tinubu, ṣe jẹ ẹlẹyinju aanu ati olufẹ araalu to.
Ọbasa sọ pe loootọ ni Tinubu ko ti i sọ pe kẹnikan bẹrẹ ipolongo oun fun ipo aarẹ ọdun 2023, ṣugbọn o ṣe pataki lati tete maa yanju awọn nnkan to ba le fa idiwọ fun Tinubu lati asiko yii lọ.
Elomi-in to sọrọ nibi ipade naa ni ẹni ti wọn fi ṣalaga ẹgbẹ BAT Foundation tuntun ọhun, Ambasadọ Aliyu Saulawa, o ni oun ko ni i fọrọ sabẹ ahọn sọ, ẹgbẹ naa maa ṣiṣẹ lati ri i pe ipo aarẹ orileede yii pada si Iwọ-Oorun lọdun 2023, ati pe ki Tinubu wa nipo ọhun, tori o ni laakaye, iriri, imọ ati okun to pọ to lati tukọ orileede yii de ebute ogo.
O ni konikaluku maa ronu bi awọn erongba ati ete ti ẹgbẹ naa wa fun yoo ṣe di mimuṣẹ lati asiko yii lọ, nipa kikan sawọn ọba alaye atawọn eekan eekan oloṣelu to maa wulo fun wọn lagbegbe tẹnikọọkan wọn wa.