Nura Walwala lorukọ ọkunrin to duro laarin awọn obinrin mẹrin yii, ẹni ọdun mẹrindinlogoji ni, oun lọkọ awọn obinrin naa.
Awọn mẹrẹẹrin ṣẹṣẹ bimọ ọwọ wọn yii ni, laarin ọsẹ mẹta ni wọn bi awọn ọmọ naa fọkọ wọn to n ṣiṣe kafinta nipinlẹ Bauchi.
Ọmọ mẹsan-an ni Nura ti bi tẹlẹ, mẹrin ti wọn ṣẹṣẹ bi yii lo jẹ ki wọn pe mẹtala bayii. Ṣugbọn Nura loun ṣẹṣẹ bẹrẹ ni o, o ni ogoji ọmọ loun fẹẹ bi, idi niyẹn toun ṣe ti fẹyawo de ori mẹrin. Wẹrẹwẹrẹ ti ọmọde n bimọ ni wọn yoo si maa bi wọn kalẹ, titi togoji toun fẹ yoo fi pe.
Nigba to n dahun ibeere lori bi yoo ṣe maa rowo tọ awọn to ti bi kalẹ yii, nigba ti ko ṣe ju iṣẹ kafinta lọ, ọkunrin yii sọ pe eeyan kọ lo n da ara ẹ bọ, Ọlọrun Ọba ni i bọ ni.
O ni oun kọ loun n bọ awọn toun ti bi yii, Allah ni. Allah naa ni yoo maa ṣeranwọ toun yoo fi bọ awọn yooku toun ṣi fẹẹ bi pẹlu. O loun ko le tori oṣi tabi ibẹru ohun ti oun yoo fun wọn jẹ koun ma waa bimọ daadaa.
Nura fi kun un pe fifẹ iyawo pupọ ki i ṣe nnkan ajoji ninu ẹbi oun, bi baba oun ṣe fẹ ẹ niyẹn, bi wọn ṣe n ṣe ninu ẹbi iya oun naa niyẹn. O loun naa ti fẹ toun dori mẹrin bayii, oun yoo bimọ kalẹ ti yoo pọ, afi bi wọn pa pe fọọti loun yoo too sinmi.