Korona tun paayan mẹẹẹdogun lọjọ kan l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

 

 

Oju l’alakan fi n ṣọ’ri lọrọ da fawọn olugbe ilu Eko bayii, latari bi arun aṣekupani Koronafairọọsi ṣe fẹẹ gbọna ẹburu ṣọṣẹ bayii, eeyan mẹẹẹdogun ni wọn tun kede pe wọn fo ṣanlẹ lawọn ibudo itọju arun Korona kaakiri ipinlẹ Eko laarin ọjọ kan pere, iku wọn ko si ṣẹyin arun buruku ọhun.

Ninu atẹjade ojoojumọ ti ajọ to n ri idena arankalẹ arun nilẹ wa (National Centre for Disease Control, NCDC) fi sode fun ti ọjọ Aje, Mọnde yii, wọn lawọn eeyan mọkandilọgọrun-un layẹwo fihan pe wọn ti lugbadi arun naa lakọtun nipinlẹ Eko lọjọ naa.

Lọjọ Aje ọhun, eeyan mẹẹẹdogun ni wọn ni Korona ran lajo aremabọ.

Iṣẹlẹ yii lo sọ iye eeyan ti arun Korona ti pa nipinlẹ Eko di ookandinnirinwo (399), awọn to si ti lugbadi rẹ ti di ẹgbẹrun marundinlọgọta o din diẹ (54,712), bo tilẹ jẹ pe eyi to pọ lara wọn ni wọn ti gbadun, tara wọn ti da ṣaṣa pada, ti wọn si ti pada sile wọn.

Atẹjada naa rọ gbogbo eeyan lati ma ṣe tura silẹ lori ọrọ arun yii, ki wọn si maa ranti awọn ofin ati alakalẹ ijọba lati dena itankalẹ arun buruku ọhun.

Leave a Reply