Birọ ba lọ logun ọdun, ọjọ kan ṣoṣo loootọ yoo ba a, lọrọ da fun ileeṣẹ to n mojuto epo bẹntiroolu nilẹ wa, Nigeria National Petroleum Commission (NNPC), ti wọn sọ fun gbogbo araalu pe ileefọpo ilẹ wa to wa ni abule kan ti wọn n pe ni Eleme, niluu Portharcourt, nipinlẹ Rivers, ti n ṣiṣẹ, awọn si ti bẹrẹ si i gbe epo nibẹ.
Ni bayii, aṣiri ti tu pe ileeṣẹ naa ko ti i fọ epo kankan, ati pe epo to ti wa ni risaafu nileefọpo naa lati bii ọdun mẹta sẹyin ni rọ sinu tanka epo mẹfa ti wọn gbe jade lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii, ti wọn ni ileeṣẹ naa ti n fọ epo, awọn si ti bẹrẹ si i gbe e fun awọn alagbata.
Wọn ni tanka epo mẹfa pere ni wọn loodu lọjọ Iṣẹgun naa, leyii to yatọ si bii tanka igba (200) ti wọn ni awọn aa maa loodu lojumọ fawọn alagbata epo.
Nigba to n sọrọ lori eto ileeṣẹ tẹlifiṣan Arise l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu yii, Akọwe awọn alẹnulọrọ ọkan ninu awọn abule ti ileefọpo naa wa, iyẹn Alese Community Srakeholders, Ọgbẹni Timothy Mgbere, sọ pe, ‘’Ileefọpo Portharcourt yii ati ibi ti wọn n ja epo si ti wọn n pe ni depo, jẹ ọna kan pataki ti o n mu ọrọ-aje gbogbo adugbo yẹn rọṣọmu. Bi ibẹ yẹn ki i ṣee figba kan da, ti iṣẹ maa n lọ nibẹ jẹ anfaani nla fun awa eeyan agbegbe yii. Ṣugbọn bi gbogbo nnkan ṣe wa lọwọlọwọ yii, mi o ro pe idi kan wa to fi yẹ ki ajọyọ kankan waye nileefọpo yii, nitori ohun ti awọn oniroyin n gbe jade nipa ileefọpo yii yatọ si ohun to n ṣẹlẹ nibẹ.
‘’Mo le fi gbogbo ẹnu sọ fun yin gẹgẹ ọkan ninu awọn ara abule yii pe ohun to ṣẹlẹ lọjọ Iṣẹgun yẹn jẹ aṣehan lasan. Mo pe e ni aṣehan nitori pe ileefọpo to wa ni Portharcourt naa ti awa maa n pe ni Area five, eyi to jẹ ileefọpo atijọ, ko ti i bẹrẹ iṣẹ kan dan-in-dan-in.
‘’Idi ti mo fi sọ bẹẹ ni pe awọn yuniiti diẹ ninu awọn ti wọn ṣẹṣẹ ṣatunṣe rẹ yii lo n ṣiṣẹ, ki i ṣe gbogbo ileefọpo yii lo n ṣiṣẹ bi a ti n sọ yii.
Loootọ ni ma a lu wọn lọgọ ẹnu pe wọn tiẹ bẹrẹ nibi kan o, ṣugbọn ohun ti ko ṣẹlẹ rara ni ọga agba ẹka to n ba araalu sọrọ, Ọgbẹni Olufẹmi Ṣonẹyẹ, n sọ fun awọn oniroyin. Mi o fẹẹ pe e ni irọ bantabanta’’.
Ọkunrin yii ni niṣẹ ni wọn n fi agbara mu awọn lọgaa lọgaa nileeṣẹ elepo ilẹ wa lati ṣaa waa ṣi ileefọpo naa, ki awọn ọmọ Naijiria le gbagbọ pe gbogbo nnkan n lọ bo ṣe yẹ. O ni gbogbo awọn lọgaa lọgaa ileeṣẹ naa ni wọn wa ni ilu Portharcourt latti ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu yii, ti wọn n lọ ti wọn n bọ, gbogbo wọn ko foju ba ooru titi ti ilẹ ọjọ Iṣẹgun ti wọn fi eto naa si fi mọ.
‘’Ni ti epo bẹntiroolu ti wọn ni ileefọpo naa ṣe, ko soootọ kankan nibẹ. Epo to ti wa ninu agba risaafu ni bii ọdun mẹta sẹyin ni wọn da sinu tanka epo mẹfa pere. Ileefọpo naa ko pese agba epo to to miliọnu mẹrin ati irinwo (1.4m).’’
O waa rọ ileeṣẹ ifọpo naa ki wọn yee rẹ awọn ọmọ Naijiria jẹ pẹlu irọ ti wọn n gbe jade fawọn oniroyin.
Mgbere ni, ‘’Ootọ ọrọ nipa bi nnkan ṣẹ ri ni mo ti sọ fawọn ọmọ Naijiria yii, ṣugbọn wọn le ma gba mi gbọ nitori awọn mi-in yoo fi ọrọ ẹlẹyamẹya bọ ọ. Ohun ti awọn kan n sọ pe ileefọpo naa ti bẹrẹ si i ta epo fun awọn alagbata, irọ to jinna sootọ ni.
Bẹ o ba gbagbe, lọjọ Aje, ọjọ kẹẹedọgbọn oṣu yii ni Ọga agba ẹka to n baraalu sọrọ nileesẹ naa, Ọgbẹni Ṣonẹyẹ kede pe ileefọpo naa ti bẹrẹ si i ṣịṣẹ, ati pe bii ọgọrun meji awọn ọkọ epo ni yoo waa gbe epo nibẹ lọjọ Iṣẹgun naa/
Wọn fi kun un pe miliọnu lọna ọgọta agba epo (60mbpd) lawọn yoo maa ṣe jade nibẹ lojumọ. Bakan naa ni wọn ni awọn ti n ṣiṣẹ lori apa keji ileefọpo naa, eyi ti awọn yoo ti maa ri agba epo to to miliọnu lọna aadọjọ (150m bpd). Ti epo tawọn yoo maa gbe jade lojumọ bi eyi ba ṣiṣẹ tan yoo le ni miliọnu lọna igba agba epo (210m bpd).
Ko tun pe ti iroyin mi-in fi jade pe owo ti NNPC fẹẹ maa ta epo tiwọn tun pọ ju ti ileeṣẹ Dangote lọ, Naira marunlelaaadọrin lo si fi ju u lọ, nitori ẹgbẹrun kan ati Naira marundinlaaadọta (1, 045), ni wọn fẹẹ maa ta jala epo kan fun awọn alagbata, nigba ti ileeṣẹ Dangote n ta tiẹ ni ẹgbẹrun kan din ọgbọn Naira (970).
Ṣugbọn to ba jẹ pe ootọ ni ohun ti Mgbere sọ yii, a jẹ pe awọn araalu ko ti i gbọdọ maa jo jagini yodo lori epo ti NNPC lawọn n fọ ni Pọta yii.