Oṣu mẹrin gbako ni obinrin aṣẹwo kan torukọ ẹ n jẹ Dooshima Anems, yoo lo lọgba ẹwọn nipinlẹ Benue, nitori ile-ẹjọ giga kan ni Makurdi ti paṣẹ pe afi ko ṣẹwọn naa gẹgẹ bi ijiya fun okunrin onibaara rẹ to ge lahọn jẹ lasiko ti wọn n ṣere ifẹ lọwọ.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọgbọnjọ, oṣu kẹsan-an, ni Adajọ Rose Iyorshe, ju Dooshima sẹwọn. Ṣugbọn ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, gan-an niṣẹlẹ igenijẹ naa waye gẹgẹ bi Agbefọba, Veronica Shaagee, ṣe sọ.
Oloṣo to ge ọkunrin jẹ naa ṣalaye pe loootọ loun ge ọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Amos Igbo, jẹ lahọn lasiko tawọn n ba ara awọn sun lọwọ.
O ni oun fi gbeja ara oun ni, nitori ẹgbẹrun meji naira pere ni kọsitọma naa san, o si fẹẹ ba oun lo pọ di ilẹ mọ ni.
O ni oun ti ṣe nọma fun Amos, nibi ti tuu taosan rẹ to san pari si, ṣugbọn kinni naa ko to o, niṣe lo tun fẹẹ ṣe si i. Dooshima sọ pe nigba toun ko gba fun un lo fun oun leṣẹẹ, to bẹrẹ si i lu oun. Koun naa le ṣe toun pada loun ṣe duro de asiko to n kẹnu bọ oun lẹnu, nigba naa loun si ge ahọn rẹ jẹ gidi ko le ba fi oun silẹ, bo tilẹ jẹ pe o ṣeṣe gan-an pẹlu boun ṣe ge e jẹ naa.
Iwa yii lodi sofin gẹgẹ bi kootu ṣe wi, iyẹn ni adajọ ṣe ni ki aṣẹwo obinrin naa lọọ ṣẹwọn oṣun mẹrin, tabi ko tun kootu ṣe fun ọse kan gbako.