Aṣeyọri ijọba mi ni kẹ ẹ fi ṣedajọ mi, ẹ ma wo aleebu rẹ-Buhari

Faith Adebọla, Eko

Olori orileede wa, Ajagun-fẹyinti Muhammadu Buhari, ti rọ awọn araalu lati ṣedajọ rẹ lori awọn aṣeyọri tijọba rẹ ṣe, ki i ṣe aleebu to wa ninu iṣejọba rẹ.

Lasiko to n ṣiṣọ loju eegun awọn iṣẹ akanṣẹ kan tijọba ipinlẹ Borno ṣe lorukọ rẹ lo parọwa naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kejila yii.

Buhari ni ọpọ nnkan rere lo ṣi maa ṣẹlẹ kijọba oun too kogba sile lorileede yii. Lara ohun rere to ni o ti n foju han bayii ni bi wọn ṣe ṣawari epo rọbi lawọn ipinlẹ Bauchi ati Gombe, lagbegbe Oke-Ọya. O ni awari naa maa din ojooro to n ṣẹlẹ lori ọrọ awọn agbegbe iwakusa epo rọbi ku, yoo si jẹ ki imudọgba waye.

O ni ọpọ awọn ọdọ orileede yii n fi ilẹ ọlọraa to yẹ ki wọn fi dako silẹ, wọn si n kọja sigboro ati awọn ilu nla, tori owo epo ni wọn n ta si.

Buhari ni: “Ẹnu ya mi, koda ẹru ba mi pẹlu, nigba ti ọjọgbọn kan sọ fun mi pe ida meji aabọ ninu ilẹ ọlọraa ti Naijiria ni la ṣi lo. Koda, mi o mọ pe bẹẹ lọrọ ri nigba ti mo wa ni gomina, ti mo ṣe minisita ati olori ijọba ṣọja.

“Ki n sọ tootọ, mi o mọ. Gbogbo nnkan ti a n ro, ti wọn n sọ fun wa, ni pe orileede elepo rọbi ni wa, ko sidii lati maa dako, tori ẹ ni ko fi si agbẹ mọ loko, ilu nla lawọn eeyan n lọ lati nawo epo rọbi.

“Ṣugbọn epo ti n di yẹyẹ bayii, a si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe wọn ti ṣawari epo ni Bauchi ati Gombe naa bayii. A maa tete ṣiṣẹ lori ẹ, a si maa tete ri awọn ọpa epo mọlẹ, ki awọn ọkọ ajagbe agbepo yee ba awọn titi wa jẹ.

“Laarin oṣu mẹtadinlogun to ṣẹku, awọn ọmọ Naijiria gbọdọ le ṣiro, ki wọn si ṣedajọ ohun rere tijọba mi ti ṣaṣeyọri ẹ, paapaa lori awọn isapa ta a ṣe nipa eto aabo, ọrọ-aje, ati eyi to buru ju, gbigbogun tiwa ibajẹ ati ikowojẹ.

“Nigba ti mo n ṣejọba ologun, mo ṣi lokun daadaa nigba yẹn, tori ọdọ ni mi, mi o si gbagbakugba. Gbogbo awọn ti mo ro pe wọn jẹ ajẹbanu la mu satimọle, awọn igbimọ oluṣewadii oriṣiiriṣii la gbe kalẹ. Gbogbo awọn gomina, minisita ati kọmiṣanna, titi kan awọn olori ajọ ati ileeṣẹ ijọba ni wọn gbọdọ kede dukia wọn faye gbọ. Ẹnikẹni ti ko ba le sọ ibi to ti rowo to fi ko awọn dukia tuntun jọ, niṣe la maa rọra fi i satimọle wẹrẹ.

“Nigba to ya, wọn mu emi naa, wọn wadii mi, ṣugbọn mi o lẹbọ lẹru, wọn si fi mi silẹ.

“Nigba ti mo bọ kaki silẹ, ti mo ko agbada wọ yii, ko rọrun lati ja ija naa rara, gbogbo okun to ṣẹku lara mi ni mo n lo bayii.

“O ba mi lọkan jẹ bi awọn afẹmiṣofo atawọn agbebọn ti wọn wa ni Ariwa/Iwọ-Oorun ati Ariwa/Ila-Oorun ilẹ wa ṣe n ṣọṣẹ kaakiri agbegbe naa, niṣe ni wọn n ba ayika tiwọn funra wọn jẹ, Oke-Ọya ni wọn si n ṣebajẹ wọn si.

“Ṣugbọn ijọba o ni i gba fun wọn, gbogbo ọna ti a fi le ba wọn ja pata la maa lo, dandan ni ka ṣẹgun awọn aṣebajẹ wọnyi.”

Leave a Reply