”Aṣiṣe gbaa ni Buhari nipo aarẹ, iru ẹ ko ni i ṣẹlẹ mọ”

Faith Adebọla

 Ẹgbẹ awọn agbaagba ilẹ Hausa, NEF (Northern Elders Forum) ti lawọn eeyan agbegbe Oke-Ọya ko tun ni i ṣe iru aṣiṣe ti wọn ṣe lọdun 2015 pẹlu bi wọn ṣe fibo gbe Muhammadu Buhari sipo aarẹ, awọn o si ni i jẹ keeyan bii Buhari tun gori aleefa lọdun 2023.

Wọn ni dipo tawọn yoo fi maa wo ibi ti ondije kan ti wa, ẹya ati ọmọ ilu to jẹ, ohun to maa pinnu ibi tawọn maa rọ ibo awọn si lọtẹ yii ni bi tọhun ṣe to si, agbara ati okun rẹ, ọgbọn ati awọn iwa amuyẹ pẹlu iriri to ti ni.

Alukoro ẹgbẹ NEF, Ọmọwe Hakeem Baba-Ahmed, lo sọrọ yii lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii, nibi ipade pataki ẹgbẹ naa ti wọn ṣe ni Arewa House, niluu Kaduna, nipinlẹ Kaduna.

Ẹgbẹ naa ni ajalu nla ni saa iṣakoso Buhari jẹ fun awọn eeyan agbegbe Ariwa, ati fun Naijiria lapapọ, o ni niṣe lawọn oloṣelu fẹtan mu awọn eeyan lọdun 2015 lati gbagbọ pe Buhari maa mu igba ọtun wa, awọn si kabaamọ lori iṣakoso ọhun. O ni Oke-Ọya ati orileede yii lapapọ buru jai lasiko yii ju bo ṣe ri ki Buhari too de lọdun 2015 lọ.

Bakan naa lo ni ọrọ idibo to n bọ yii ki i ṣe ti eeyan agbegbe kan, gbogbo ọmọ Naijiria to ba kunju oṣunwọn lo lẹtọọ sipo aarẹ, ibaa jẹ lati apa Ariwa tabi Guusu, ibi yoowu ki tọhun ti wa kọ lo ṣe pataki, ko ṣaa ti jẹ aarẹ Naijiria ni, ki i ṣe aarẹ agbegbe kan.

“Ati ẹni to wa lati Ariwa, ati ẹni to wa lati Guusu, ẹtọ kan naa la ni, ko sẹni ti ko le jade dupo ninu wọn, ṣugbọn awọn eeyan Ariwa gbọdọ kiyesara gidigidi lọtẹ yii, lasiko ibo ọdun  2023.

“Ara Oke-Ọya kan ko gbọdọ foju di wa, pe ẹnikan wa lati Oke-Ọya ko tumọ si pe oun la maa dibo fun, tori aṣiṣe to gbe wa de ọdọ Aarẹ Buhari yii niyẹn, a o si ni i ṣe iru aṣiṣe bẹẹ mọ. Bi ondije kan ba wa lati Oke-Ọya, o gbọdọ jẹ ẹni to daa ju awọn ondije to ku lọ, ka too le dibo fun un.

“Ki i ṣe keeyan kan wa lati Oke-Ọya, o gbọdọ jẹ ẹni to daa ju lọ fun Oke-Ọya, ati fun gbogbo Naijiria. Loootọ la n wa aarẹ, to ba ja lati Ariwa la ti ri ẹni to daa ju, ko buru, bo ba si jẹ ibomi-in ni, ko ṣaa ti jẹ ẹni to daa ju awọn yooku lọ.”

Bakan naa ni ẹni to ṣe kokaari ipade naa, Ọjọgbọn Ango Abdullahi, fesi si ọrọ ti Aṣiwaju Bọla Tinubu sọ lọsẹ to kọja l’Abuja, pe afọbajẹ loun, ko si sofin to sọ pe afọbajẹ ko le di ọba, tori naa, oun maa dupo aarẹ. Abdullahi sọ pe iha Ariwa orileede yii la le pe ni afọbajẹ Naijiria, ki i ṣe ẹnikan.

O ni, “Mo gbọ tẹnikan ni afọbajẹ loun, oun si fẹẹ jọba wayi. Ẹ jọọ, ki i ṣe pe mo fẹẹ ṣegberaga o, bẹẹ ni mi o yaju sẹnikẹni, ṣugbọn Ariwa lo ti wa nipo afọbajẹ orileede yii lọjọ to ti pẹ.”

“Mo rọ awọn eeyan Oke-Ọya pe ki wọn gbọnti nu ninu ọrọ to le mu’nu biiyan tawọn eeyan agbegbe Guusu kan n sọ, wọn n sọrọ bii pe awọn ni apaṣẹ demokiresi Naijiria. Irọ ni, ẹni to ba daa ju lọ lawọn eeyan Ariwa maa yan lolori.

“Aparo kan ko ga ju ọkan lọ, ẹtọ kan naa ni Ariwa ati Guusu ni lati dupo aarẹ nigbakuugba, ohun to ja ju ni bi tọhun ṣe kunju oṣuwọn si, bo ṣe jẹ oloootọ si, ati bo ṣe maa le pa awọn ofin ati ilana iṣakoso mọ to.”

Ọkunrin naa ni inu oun dun si bi ẹsẹ awọn agbaagba ilẹ Hausa ṣe pe sipade naa, awọn si ti fori kori lati wa ojuutu sawọn ọrọ to takoko nipa eto iṣelu ati idibo to n bọ, ati pe iru ipade yii maa maa waye loorekoore ni.

Leave a Reply