‘Aṣigbọ ni, a ko fi gbedeke le ogun Boko Haram’

Ileeṣẹ ọmọ-ogun ofurufu ilẹ yii ti sọ pe aṣigbọ gbaa ni iroyin to jade lanaa lori ọrọ ti olori awọn, Ọgagun Sadique Abubakar, sọ nipa gbedeke ọdun yii lati fopin si ogun Boko Haram.

Ninu atẹjade ti adari ẹka iroyin ileeṣẹ naa, Ọgagun Ibikunle Daramọla, fọwọ si lonii, ọjọ Aiku, Sannde, o ni Abubakar ko sọ pe awọn yoo fopin si ogun Boko Haram lọdun yii, o kan fi ọrọ to sọ ṣe koriya fawọn ọmọ-ogun ni.

Atẹjade naa ni, ‘’Lati jẹ ki gbogbo eeyan mọ, ọrọ ti adari ileeṣẹ yii sọ pe ‘laipẹ, o kere tan, ko too di opin ọdun yii, a maa pari iṣẹ ta a waa ṣe, o si pẹ tan, opin ọdun yii…’ ko tumọ si pe awa la maa da pari ogun naa. Nnkan to tumọ si ni pe a n fun awọn ọmọ-ogun wa ni gbedeke ko le jẹ koriya fun wọn, ki wọn si le gbaju mọ iṣẹ ki eyi le wa si imuṣẹ.

‘’Afojusun wa ni pe, pẹlu ọrọ yii ati ajọṣepọ pẹlu awọn ẹka ọmọ-ogun to ku, ifarajin yoo wa lati jagun ṣẹgun.’

About admin

Check Also

2023: Ẹgbẹ TOTT rọ Tinubu atawọn oludije yooku lati panu pọ gbe Ọṣinbajo kalẹ

Ọrẹoluwa Adedeji Ẹgbẹ kan, The Ọsinbajo Think Tank (TOTT), ti parọwa si aṣaaju ẹgbẹ oṣelu …

Leave a Reply

//ugroocuw.net/4/4998019
%d bloggers like this: